Belarus ní ààyè ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàrín Ukraine àti Russia ti wà níkàlẹ̀

Russia Ukraine

Oríṣun àwòrán, @Belarus Foreign Ministry

Belarus ní ààyè ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàrín Ukraine àti Russia ti wà níkàlẹ̀

Belarus ni eto gbogbo ti to fun ibudo ipade ipẹtusaawọ laarin Ukraine ati Russia pẹlu bi iṣigun Russia wọ Ukraine ṣe wọ ọjọ karun un.

Ukraine ti gba lati ran awọn aṣoju lọ si ibudo naa to wa nitorsi aala ilẹ Ukraine ati Belarus bi o tilẹ jẹ oe iroyin n sọ pe olori ilẹ naa fẹ ran awọn ọmọ ogun orilẹede rẹ pẹlu lati darapọ mọ ikọlu naa.

Igbese wo ni wọ́n ti gbe bayi lori ọ̀rọ̀ Russia ati Ukraine?

” A ti pese aye ipade silẹ fun ipẹtu saawọ naa, a n reti dide awọn aṣoju ijọba orilẹede mejeeji ni bayii” ni ọrọ ti minisita f’ọrọokeere ni Belarus fi sita loju owo ayelujara pẹlu aworan tabili gigun kan pẹlu ọpọlọpọ aga oẹlu aṣia orilẹede Ukraine ati Russia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Anatoly Glaz, to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọrọ okeere orilẹede naa sọ pe

” ipade naa yoo bẹrẹ laipẹ ni kete tawon asoju gbogbo ba ti de”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ukraine ti leri leka oe awọn ko ni jọwọ ohunkohun nibi ipade naa, bẹẹ ni aarẹ Volodymyr Zelensky naa ti sọ pe ohun ko ni ireti pe ijiroro naa yoo so eso rere.

“Gẹgẹ bi ise mi, emi o reti pe ọsan ipade yii lee so didun, ṣugbọn ẹ jẹ ki wọn gbiyanju.”