NÍ YÀJÓYÀJÓ FIFA àti UEFA fòfin de Russia àti Belarus láti kópa nínú ìdíje kankan ní àgbáyé

Gẹgẹ bi awọn ọmọ ogun Russia ṣe tun n sunmọ olu ilu orilẹede
Ukraine sii, awọn alaṣẹ tin ke si awọn
araalu lati ṣe ohun gbogbo ti wọn ba le ṣe lati dena awọn ọmọ ogun Russia lati
wọle.

To fi mọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ abo ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ
abẹnu lo n rọ gbogbo awọn olugbe Kyiv lati maa fi igbesẹ awọn ikọ ọmọ ogun ọhun
ti wọn ba ko firi rẹ to awọn leti ati pe ki awọn naa lo gbogbo ọgbọn ti wọn ba
le lo lati ba ti awọn ọta jẹ.

Nibayi, wọn ti ṣe iwe pelebe kan jade to n ṣalaye ni sisẹntẹle
bi eeyan ṣe le ṣe ado oloro pẹlu epo bẹntiroo wọn si ti fi sita bi atẹjade loju
opo ayelujara wọn.

Wọn ti ko ibọn ẹgbẹrun mejidinlogun sita ni ilẹ Kyiv fun
gbogbo awọn to ba nifẹ sii lati da abo bo olu ilu wọn.

“A ti n ṣi awọn nkan ijagun Ukraine wọ ilẹ Kyiv bayii lati
da abo bo ibẹ. Mo n pe gbogbo awọn olugbe Kyv – ẹ jọwọ ẹ ma ya fotọ tabi fidio iwọle
rẹ, eyi ṣe pataki lati da abo bo ilu wa”.