Ẹ̀bẹ̀ béèlì Abba Kyari kò ba mọ́, yóò lo ọjọ́ mẹ́rìnlá si ní àhámọ́ NDLEA – Iléẹjọ́

Abbas Kyari

Oríṣun àwòrán, @FestusGreen

Ile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Abuja ti kọ lati gba beeli Abba Kyari lori ẹsun gbigbe oogun oloro ti NDLEA fi kan.

Adajọ Inyang Ekwo sọ pe akoko ti lọ lori iwe ẹbẹ ti Kyari kọ siwaju ile ẹjọ ọhun, nitori naa, oun fun NDLEA ni ọjọ mẹrinla si lati fi Kyari si ahamọ, ko le tẹsiwaju ninu iwadii to n ṣe.

Adajọ Ekwo sọ pe ṣaaju ni ile ẹjọ kan ti kọkọ ṣedajọ lọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2022 pe afurasi naa ṣi le wa ni ahamọ NDLEA.

Amọ o ni oun ti ṣetan lati gbọ ẹjọ rẹ to pe tako NDLEA lori ẹtọ rẹ labẹ ofin, amọ igbẹjọ ọhun yoo di ẹyin ọjọ mẹrinla.

Lẹyin naa lo sun ẹjọ ọhun si ọjọ karundinlogun, ọsu Kẹta, ọdun 2022 yii.

O ni “Mo kọ lati gba beeli afurasi lọwọ yii.”

Nigba to n sọrọ lori ilera Kyari, adajọ ọhun ni “NDLEA gbọdọ gba olupẹjọ laaye lati maa lo awọn oogun rẹ ni ahamọ to wa gẹgẹ bii aṣẹ ti ile ẹjọ pa ṣaaju lọjọ kejilelogun, oṣu Keji.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹjọ wo ni Kyari pe ṣaaju?

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ni Kyari pe ajọ NDLEA lẹjọ lori pe wọn fi ẹtọ oun dun oun gẹgẹ bii ọmọ Naijiria, ati lori bi wọn ṣe fi oun si atimọle.

Ninu iwe ipẹjọ naa lo ti ni ki ile ẹjo kan an nipa fun NDLEA lati fun oun ni owo gba ma binu ti iye rẹ to ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lori bi wọn ṣe tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ.

O tun ni oun n fẹ ki NDELA tọrọ aforiji lọwọ oun ninu awọn iwe iroyin to gbajumọ kaakiri Naijiria.

Bi Kyari ṣe dero atimọle NDLEA:

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ni NDELA kede pe Kyari wa ni ahamọ oun lori ẹsun pe o n ni ibaṣepọ pẹlu awọn to n ta oogun oloro.

Ikede naa lo waye lẹyin oṣu diẹ ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI sọ pe ki ọga ọlọpaa naa wa sọ tẹnu rẹ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu afurasi onijibiti ori ayelujara, Hushpupi.

Awọn ọlọpaa mẹrin mii ni NDLEA fẹsun gbigbe oogun oloro naa kan, yatọ si Kyari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ