Aiyedatiwa di gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo tuntun lẹ́yìn ikú Akeredolu

Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/Facebook

Yọruba bọ wọn ni bi ẹni ba ku, ẹni nii ku.

Eyi lo difa fun Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa ti adajọ agba ipinlẹ Ondo ti ṣe ibura fun bayii gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ondo.

Owurọ Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni iroyin naa jade sita pe o ku lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.

Ni nnkan bi aago meji oru la gbọ pe o mi eemi igbẹyin.

Ṣaaju iku rẹ, Gomina Akeredolu ti n ṣe aisan fun ọpọlọpọ oṣu.

Awọn iroyin kan sọ pe aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ, Leukemia, ni gomina naa ni.

Lati bi ọdun kan si lo ti wa ni idubulẹ, ti ko le ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi gomina.

ijọba ipinlẹ Ondo ti tan imọlẹ si ọrọ naa pẹlu atẹjade ti wọn fi sita lori iku Akeredolu.

Ninu atẹjade ti Bamidele Ademola-Olateju, Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, fi sita, o ni gomina Akeredolu fọwọ́ rọri ku ni owurọ kutukutu Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

“Gomina Akeredolu jẹ ipe ayeraye nibi to ti n gba itọju ni orile-ede Germany.

“O ku nitori aisan jẹjẹrẹ to mu ni koropọn.”

Ọgbẹni Ademola-Olateju sọ pe awọn ti kọ lẹta ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu, lati fi iroyin iku gomina to o leti.

O ni awọn yoo kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ.

Adajọ agba ipinlẹ Ondo ṣeto ibura fun Aiyedatiwa

Lẹyin ti iroyin iku gomina Rotimi Akeredolu gbalẹ kaakiri tan ni a n gbọ wuruwuru lọsan an Ọjọru kan naa ti Akeredolu di oloogbe wi pe eto ibura fun Aiyedatiwa gẹgẹ bi gomina tuntun ipinlẹ Ondo yoo waye ni irọlẹ.

Ere ni awada ni leto naa fi gberasọ niluu Akure eleyii ti awọn ileeṣẹ tẹlifisan ṣi gbe eto naa bi o ti n lọ lọwọ.

Bayii ni adajọ agba ipinlẹ Ondo, Olusegun Odusola dari eto ibura fun Aiyedatiwa gẹgẹ bi gomina ipinlẹ lẹyin ti Akeredolu jẹ Ọlọrun ni pe.

Ninu ọrọ rẹ, Aiyedatiwa ni ”pẹlu ọkan to wuwo ni mo fi gba lati di gomina ipinlẹ Ondo lonii ati lati tukọ ipinlẹ yii lẹyin iku gomina wa ati ọga mi, Arakunrin Oluwarotimi Odunayo Akeredolu.”

Awọn alẹnulọrọ mii to wa nibi ayẹyẹ ọhun ni awọn adajọ mii, awọn lọgalọga lẹnu iṣẹ ọba, alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Aiyedatiwa di adelé gómìnà Ipinlẹ Ondo lọjọ kẹtala oṣu Kejila ọdun 2023

Abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ondo kede pe igbakeji gomina ipinlẹ naa, Lucky Aiyedatiwa, ti di adele gomina lọjọ kẹtala, oṣu Kejila, ọdun 2023, titi di ọjọ ti Gomina Oluwarotimi Akeredolu yoo pada de lati isinmi to lọ.

Abẹnugan ile ọun, Olamide Oladiji, lo sọ eleyi ninu lẹta kan to fi soju opo atẹjiṣẹ WhatsApp, lẹyin ti agbẹnusọ ile, Olatunji Oshati, ti fidi rẹ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba.

Oladiji wni “ni atẹle amọran dokita pe ki Gomina Oluwarotimi Akeredolu o lọọ sinmi lẹyin ti alaafia ti n de sagọ ara rẹ, gomina naa lo ti fiwe ṣọwọ sile aṣofin lati fi to wọn leti pe oun n lọ fun isinmi.

“Gẹgẹ bi lẹta ọhun ṣe wi, igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa, ni yoo maa ṣe ojuṣe gomina bii adele titi di igba ti iwe miran yoo de latọwọ gimnina pe ko ri bẹẹ mọ.

“Isinmi yi ni ireti wa pe yoo bẹrẹ lọjọ kẹtala oṣu kejila, ọdun 2023.”

Oladiji fi kun un pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun alaafia to de sagọ ara gomina ni kia ati pe oun nigbagbọ pe yoo pada sẹnu iṣẹ laipẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, awuyewuye ti n waye lori ipo ti ilera gomina Akeredolu wa.

Ṣaaaju ni Akeredolu ti kọkọ tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede Germany, nibi to ti lọ gba itọju aisan kan ti ko darukjọ fun awọn ọmọ ipinlẹ Ondo.

Asiko to kọkọ lọ gba itọju naa ni o fa ijọba kalẹ fun Aitedatiwa.

Amọ ni kete to de lati irinajo ni o gba iṣẹ lọwọ awọn agbenusọ igbakeji rẹ, ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa si gbiyanju lati yọ Aiyedatiwa nipo bii jiga ko to tọrọ aforiji lọwọ gomina.