Afẹ́fẹ́ òjò tó lágbára ṣọṣẹ́ l’Ogun, sọ ogójì agbègbè sínú òkùnkùn

Afẹfẹ ojo nla kan to gbilẹ ni agbegbe Sango Otta ni ijọba ibilẹ Afo-Odo/Ota ni ipinlẹ Ogun, ti sọ ogoji agbegbe sinu okunkun bayii.

Iṣẹlẹ naa lo hu opo ina, to si tun ba ọpọlọpọ waya ina, eyi to wo soju titi ijọba, to si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Ileeṣẹ to n rí si ina mọnamọna ni agbegbe naa, Ibadan Electricity Distribution Company tí fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, tí wọn si n rọ awọn olugbe agbegbe naa lati yago fun awọn opo ina ati waya ina to wo soju títí naa.

Ninu ikede ti wọn fi sita, ileeṣẹ to n pina mọnamọna, IBEDC ni “nítorí awọn opo ina to dawo lẹyin ti ojo aroroda to rọ ni agbegbe Sango Otta ati Mowe, awọn onibara wa ni awọn agbegbe wọnyi bi lyana lyesi, Osuke Town, Egan Road, lyana Ilogbo, Ijaba, Ijagba, Itele, Lafenwa, Singer, Joju, Alishiba, Oju Ore, Tollgate, Eledi, Akeja, Abebi, Osi Round About, Ota Town, Ota Industrial Estate, Igberen, lju, Atan, Onipanu, Obasanjo, Lusada, Arigba, Odugbe, Ado-Odo, Igbesa, Owode, Olokuta, Hanushi, Bamtish Camp Lufiwape, Eltees Farm, August Engineering, Spark Cear Soap Ayetoro, Amazing Grace Oil, Christopher University, Royal Garden Estate, Pentagon Estate ati awọn agbegbe mii to sun mọ awọn agbegbe yii ko ni anfani lati lo ina mọnamọna lasiko yii.