“Ìdí rèé tí a kò ṣe tíì kéde Olubadan tuntun nílẹ̀ Ibadan”

Ladoja ati Ajibade

Ẹkẹrin Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Hamidu Ajibade ti salaye idi ti awn igbim afbaj nil Ibadan ko se tii kede ba tuntun fun il Ibadan.

Ọba Ajibade, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu Akọroyin BBC Yoruba salaye pe, eto yiyan Ọba miran gbọdọ bẹrẹ lẹyin ọjọ kọkanlelogun ti Olubadan to wa lori oye ba gbeṣẹ.

O fikun pe oju ko kan awọn igbimọ afọbajẹ nilẹ Ibadan lati yan Olubadan tuntun.

O ni gbogbo awuyewuye to n waye lori ẹni to kan lati jẹ Olubadan tuntun ko tu irun kankan lara awọn agba oye ati oriade ti wọn wa ni ori ila lati jẹ Olubadan.

Ta lo ni ẹ̀tọ́ lati pe ipade ìgbìmọ̀ afọbajẹ lati kede Olubadan tuntun laarin awọn agba oye n‘Ibadan?

Ninu ofin ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan, bi Olubadan kan ba wọ aja, ẹni to dagba ju ni igun oye ti ọba jijẹ ko kan ni yoo pe ipada awọn afọbajẹ.

Nibẹ si ni wọn yoo ti panupọ kede ẹni ti Olubadan kan ni igun ti oye naa kan.

Amọ nigba ti ba Lekan Balogun waja, ti wọn si ti sin-in, ọpọ eeyan lo n ro pe agba oye Rashidi Adewolu Ladoja, tii se tun Olubadan lo yẹ ko pe ipade lati kede Oloye to dagba ju ni igun Balogun.

Sugbọn se ni iroyin gbalẹ kan pe awọn oloye to jẹ ọba alade nilẹ Ibadan ko fara mọ pe ki Ladoja pe ipade nitori awijare pe o kọ lati gba ade, gẹgẹ bi awọn agba oye yoku ti se.

A gbọ pe eyi lo n se okunfa idaduro to wa nidi kikede ẹni ti oye Olubadan kan, tii se agba oye Owolabi Olakuleyin.

Nigba to n fesi lori ọrọ naa, Hamidu Ajibade ni eyi ko ri bẹ́ẹ̀.

“Ladoja ni yoo pe ipade, ti awa afọbajẹ yoku yoo si fọwọsi”

Ọba Ajibade nigba to n fesi si ọ̀rọ̀ amofin Lana salaye pe, gbogbo awuyewuye lori ẹni ti o le fọba jẹ ko lẹsẹ nlẹ nitori pe ofin ipinlẹ Oyo fun awọn Ọba ilẹ Ibadan lagbara lati ṣe ipade yan Ọba tuntun.

Nigba to n sọrọ lori akoko ti igbimọ afọbajẹ nilẹ Ibadan yoo joko lati se ipinnu lori ẹni ti oye Olubadan kan, Ọba Ajibade nii:

“Agba Oye Adewolu Ladoja, ẹni to ti fi igbakan ri jẹ Gomina ipinlẹ Oyo, ni yoo pe ipade ti asiko ba ti to, ti awọn Ọba yoku yoo ṣi fọwọsi yiyan ẹni ti wọn ba fẹnu ko lati jẹ Ọba tuntun.

Ọba Ajibade ni “ẹni ti o kan lati jẹ Olubadan n sinmi lọwọ ni, gbogbo wa la mọ wi pe Ọba Olalekan Olakulehin ti dagba, wọn sinmi lọwọ ni.

Agbalagba ni wọn, nigba ti o ba to akoko, wọn yoo pe ipade ti gbogbo wa yoo si ri wọn “

“Ọrọ ọba jijẹ nilẹ Ibadan ko kan amofin Folorunso Lana, a ko fi ọrọ lọ ọ, ohun ti yoo jẹ bii amofin, lo n wa”

Saaju ni Amofin kan nilẹ Ibadan, to tun jẹ Amofin agba ati Kọmisana feto idajọ tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Gbade Lana ti sọ pe gbogbo awọn Ọba nilẹ Ibadan ko lẹtọ lati yan Ọba tuntun.

Gẹgẹ bi Lana ti sọ, ofin ko faye gba awọn ọba naa lati gbe igbesẹ ọhun.

Amọ nigba to n fesi lori ọrọ yii, Ọba Ajibade ni “Awa igbimọ afọbajẹ nilẹ, Ibadan ko kesi ẹnikẹni lati ba wa da si ọrọ to wa nilẹ yii.

Sugbọn kaluku naa lo n wa nnkan ti yoo jẹ ,ní wọn fi n da si ọrọ naa, awọn naa n wa bi wọn yoo ṣe fi kaun si ọbẹ wọn, ti yoo fi dun ni.

Lana n sọrọ yii lati fi mu agbega ba iṣẹ rẹ ni , aburo wa ni, a ti mọ bí nnkan ṣe `n lọ.

Ko si ninu ijoye, ko si ninu Ọba,iṣẹ ti wa ti a n ṣe nu, isẹ tirẹ ni iṣẹ agbẹjọro, ti wọn ba si gba nisẹ agbẹjọro, o di dandan ko ṣe iṣẹ owo rẹ”

“Awa ti a yan Ọba tuntun ko kanju, ti asiko ba to, ijọba ipinlẹ Oyo ba yoo fi Ọba jẹ nilẹ Ibadan”

Ọba Ajibade tẹsiwaju wi pe “Amofin Lana nikan naa lẹ maa gbohun rẹ ni gbogbo igba, Lana loni, Lana lọla, ọna ti oun naa fi n jẹun nu, ko ni iṣẹ miran.

Gomina Seyi Makinde lo lẹtọ lati fọwọsi yiyan Ọba tuntun, aṣa ni awa afọ̀bajẹ́ ni lọwọ, Gomina lo ni ofin lọwọ, ofin ipinlẹ Oyo, ọwọ rẹ lo wa.

Gbogbo ohun to jẹ mọ ọrọ lọba lọba, ọwọ gomina lo wa, agbẹjọro ki ṣe alaṣẹ wa, Gomina ni alaṣẹ wa.

Gomina lo fi wa jọba, o si tẹlẹ ofin, ko si bi ilu o ti wa, ti a ko ni ma ri awọn kọọ̀kan ni gbogbo ibi na lo wa, kolorun ma ṣe wa ni ẹniti o ma n da nkan ru”.

O tẹsiwaju pe awọn ti yoo yan Ọba tuntun ko kanju, ti asiko ba to, ti ijọba ipinlẹ Oyo ba ti ṣetan lati fi Ọba jẹ nilẹ Ibadan.

O ni wọn yoo kede Olubadan tuntun, ti yoo si foju han sita fun gbogbo eeyan lati ri i.