‘Ramadan wà láti “charge” wa ni, fáìlì ẹlòmíì ti gaa fún ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bátíìrì wọ́n ti jò’

‘Ramadan wà láti “charge” wa ni, fáìlì ẹlòmíì ti gaa fún ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bátíìrì wọ́n ti jò’

Àǹfàní tó pọ̀ ló wà nínú gbígba ààwẹ̀ l’óṣù Ramadan – Alfa

Abdulmumeen BBC Yoruba ba Alfa Abdulmumeen Abdulbakere to jẹ adari ẹsin Islam ati olukọ ni Kọlẹẹji ti Arabic ẹkọ nipa ẹsin Islam sọrọ ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara.

Alfa jẹ ko di mimọ pe gbogbo ẹni tó bá gba ààwẹ̀ Ramadan yìí pẹ̀lú ímáánì yoo ri anfani pupọ jẹ nibẹ. O tun sọ awọn anfani to wa ninu gbigba aawẹ Ramadan lara rẹ si ni pe gbogbo ẹṣẹ ti wọn ba ti ṣẹ fun ọdun kan sẹyin yoo gba idariji.

“Too ba le fi aawẹ ri idariji gba, o ti di ọmọ Aljana nuu”

Alfa Abdulmumeen Abdulbakere

Abdulmumeen ni lati oṣu mọkanla sẹyin ti aawẹ Musulumi ti waye gbẹyin, faili ẹlomii lọdọ Ọlọhun ti ga, o ti kun fun ọpọ ẹṣẹ.

“Gbogbo ẹni to ba gbaa pẹlu imaani, to ba gba a pẹlu wipe o n reti ẹsan lọdọ Ọlọhun Ọba, yoo ri idariji ẹṣẹ rẹ gba”. O ni ẹni to ba si ti ri idariji ẹṣẹ, o ti di ọmọ Aljana nuu.

Alfa ni ara anfani ti aawẹ mu wa ni pe o da bi igba ti eeyan lo foonu titi ti batiiri rẹ fi ku ni, “to ba ti dun to lo lo lo, yo wiiki yoo si ni ko “chargi ẹ”, abi o ye yin bayii nisinyi, Ramadan wa lati charge wa fun ibẹru Ọlọhun.”

Abdulmumeen Abdulbakere

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí