Ètò ọrọ̀ ajé United Kingdom wọ ‘recession’ – Wo nǹkan tí èyí túmọ̀ sí

Aworan awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi lori afara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin lọdọ awọn alaṣẹ nilẹ Gẹẹsi ti fihan pe laarin oṣu mẹta to kẹyin ọdun 2023, eto ọrọ aje ilẹ naa dẹnukọlẹ lẹyin ti adinku ba eto ọrọ aje.

Apapọ iye owo to n wọle nilẹ naa ladinku deba ni ida 0.3% laarin oṣu Kẹwaa ati oṣu Kejila.

Eyi waye lẹyin iṣubu ọrọ aje ilẹ naa kan to waye laarin oṣu Keje ati oṣu Kẹsan-an.

Ti iye to n wọle fun ilẹ Gẹẹsi ba dẹnukọlẹ laarin oṣu mẹta lera wọn, eyi tumọ si pe ọrọ aje ilẹ naa ti dagun niyẹn. Ipo naa ni awọn onimọ nipa ọrọ aje n pe ni Recession.

Ọrọ yi yoo jẹ ohun ti ko ni dunmọ olootu ijọba Rishi Sunak.

Idi ni pe o pinnu lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ilẹ naa gẹgẹ bi ọkan lara ẹjẹ to jẹ fun araalu ninu oṣu Kinni, ọdun 2023 to gba iṣakoso.

Ẹwẹ, oṣu mẹta lo ku bayii ti Minisita feto ọrọ aje Jeremy Hunt yoo ṣe agbekalẹ aba iṣuna niwaju ile.

Minisita fun ọrọ abẹle, Rachel Reeves, sọ pe iroyin yi tumọ si pe ipinnu olootu ijọba Sunak to ṣe lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ti foriṣanpọn.

Apapọ owo to n wọle fun ijọba orilẹ-ede, eyi ti wọn n pe ni GDP, jẹ ọna kan gbogi ti ijọba le fi tọka si pe awọn n mu ki eto ọrọ aje gbooro si tabi dinku.

Amọ bo ba ti dẹnukọlẹ eyi tumọ si pe ijọba ti kuna ninu eto ọrọ aje niyẹn.

Ti owo pupọ ba wole si apo ijọba, o tumọ si pe ijọba yoo ri owo daada lati pese awọn ohun amayedẹrun bi eto ẹkọ ati ilera to peye.

Ijọba a tun maa lo GDP yii lati mojuto iye owo ti wọn ba ya ni afiwe apapọ ọrọ aje ilẹ naa.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ lati ẹka to n ṣeto owo nina ni United Kingdom naa fihan pe, Minisita feto ọrọ aje n foju sun ọna kan gbogi ti yoo fi mu alekun ba iye ti ijọba n na fun araalu.

eyi lo ni yoo duro gẹgẹ bi ọna ti adinku yoo fi ba iye owo ori ninu aba ofin iṣuna ti wọn yoo gbe kalẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta.

Afojusun iye ti ijọba fẹ na fun araalu ti lọlẹ nitori pe owo ele ti ijọba yoo san lori owo to ya ti n lekun si.

Ijọba ko ti kede ipinnu lori ọrọ yi.

Ninu ọrọ rẹ lori ọrọ GDP yi, Ọgbẹni Hunt sọ pe ”Bi iye owo ele ṣe n ga si , o ṣeeṣe fun banki England ko mu alekun owo nkan walẹ. Ko jẹ tuntun ka ni ifasẹyin diẹ ninu ọrọ aje wa”

Ruth Gregory, to jẹ igbakeji ọga onimọ ọrọ aje ni Capital Economics sọ pe ”o ṣeeṣe ki iroyin to waye yi mu ki banki England gbe igbesẹ to jọ mimu adinku ba iye owo ele banki wọn.”

Amọ o fi kun pe mimi kan o mi banki naa lori nnkan to le jẹ ifasẹyin diẹ tabi eleyi ti o jẹ ọlọjọ kukuru.

Awọn iroyin to jade laipẹ yi fi han pe iye ti owo ọja fi lọ soke taa mọ si inflation, ko kọja ida mẹrin ninu ida ọgọrun ninu oṣu Kinni ọdun.

Saaju ni Banki England ti n mu alekun ba iye owo ele lọna ati dẹkun alekun iye owo ọja to wa ni ida 5.25% lati oṣu Kẹjọ ọdun to kọja.

Titi ti ọdun fi opari gbogbo idagbasoke to deba eto ọrọ aje ko ju ida 0.1% lọ.

Itunmọ idẹnukọlẹ ọrọ aje

Idẹnukọlẹ tabi ifasẹyin ọrọ aje a maa waye nigba ti iye owo ti orileede ba n pa wọle lapapọ ba ni dinku lọpọ igba laarin oṣu mẹta – mẹta lera wọn.

GDP gẹgẹ baa ṣe sọ ni apapọ iye owo to wọle lori ọja ati awọn iṣẹ ti wọn ṣe ninu orileede kan tabi eleyi ti wọn ta fun awọn orileede mii.