Dapo Abiodun ṣàbẹ̀wò sí ọkùnrin tí ìbọn bá lásìkò ìwọ́de l‘Abeokuta

Gomina Dapo Abiodun ati ọkunrin ti ibọn ba

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti se abẹwo si ọkunrin kan ti ibọn ba lasiko iwọde to waye nilu Abeokuta lọjọ isẹgun.

Iwọde naa lawọn eeyan n se lati fi ẹhonu wọn han si aisi owo naira tuntun nita ati ọwọn gogo epo bẹntrolu.

Akọroyin BBC Yoruba wa nile iwosan ijọba Federal Medical Centre, FMC, nilu Abeokuta, ti ọkunrin ọhun, ti wọn pe orukọ rẹ ni Mikel ti n gba itọju.

O si ti foju han gbangba pe ara ọkunrin naa ti n ya, ti wọn si ti n tọju rẹ pupọ, tawọn ẹbi rẹ naa si ti duro tii nile iwosan.

Ninu ọrọ rẹ, gomina Dapo Abiodun ni oun bawọn araalu atawọn mọlẹbi ọkunrin ti ọta ibọn ba naa kẹdun, ẹni to ti n gba itọju to peye lọwọ

O wa seleri pe ijọba oun yoo san gbogbo owo itọju ọkunrin naa nile iwosan oun.

Gomina Dapo Abiodun ati ọkunrin ti ibọn ba

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

Iwọde kọ ni ọna lati wa ojutu si isoro ọwọn gogo naira ati epo – Dapo Abiodun

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lasiko abẹwo rẹ naa, gomina Dapo Abiodun rọ awọn araalu lati sinmi iwọde lori awọn isoro to n koju wa.

O ni iwọde kọ ni ọna lati wa ojutu si isoro ọwọn gogo naira ati epo to n ba ilẹ yii finra.

Bakan naa lo salaye ọpọ akitiyan ti ijọba rẹ n se lati ri daju pe ohun gbogbo pada bọ sipo nipinlẹ naa.

“Ẹyin ọdọ ati akẹkọọ, mo bẹ yin ni lati bomi suuru mu, fifọ banki ati biba ẹrọ ATM jẹ kọ lo le yanju awọn isoro yii.

O si n rọ awọn araalu pe gomina yin n sa gbogbo ipa rẹ lasiko yii lati mu ki igbe aye rọrun fun yin.

A ti ba aarẹ Buhari sọrọ pẹlu gomina banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, to fi mọ ẹgbẹ awọn osisẹ ile ifowopamọ , ti eyi yoo si mu eso rere jade.”

Gomina Dapo Abiodun ati ẹbi ọkunrin ti ibọn ba

Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR

“Ẹtọ banki CBN ni lati se atunto owo amọ kii se araalu lo yẹ ko jiya igbesẹ naa”

Gomina Dapo abiodun tẹsiwaju pe lootọ ni banki CBN ni ẹtọ ati asẹ labẹ ofin lati se atunse owo Naira amọ eyi ko yẹ ko mu inira nla bawọn ọmọ orilẹede yii.

O ni airi owo beba naa gba lawọn ile ifowopamọ ati lẹnu ẹrọ ATM pẹlu epo bẹntiroolu to wọn lo ti n mu ki ara kan awọn araalu.

Gomina Abiodun, ẹni to tun kede abẹwo rẹ naa soju opo Twitter rẹ wa tun fọwọ gbaya pe eto idẹrun araalu ni oun yoo mu ni ọkunkundun.