A kò mọ̀ọ́mọ̀, bàálù ìjagun tó pa àwọn eèyàn Yobe náà ṣèèṣì jábọ́ ni- Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà

Baalu

Oríṣun àwòrán, @Nig Airforce

Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ti fi ikede sita pe nitootọ ni baalu ijagun kan ja ni ilu Buhari ni ipinlẹ Yobe.

Saaju ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ti kọkọ sọ pe eeyan mẹ́wàá lo ba iṣẹlẹ naa rin.

Ni kete ti iṣẹlẹ yioi ṣẹlẹ ni ana ni ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ pe irọ ni.

Wọn ni ko si ohun to jọ beẹ.

Sugbon bayii, ileeṣẹ ologun ofurufu ni Naijiria ti kede pe lootọ lo ṣẹlẹ.

Wọn ti fi atejade sita pe asise ni iṣẹlẹ naa to fa ijamba to mu ẹnmi awọn eniyan kan lọ.

Ogagun Edward Gabkwet to jẹ adari agba ni NAF lo buwọlu atẹjade naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ogagun Edward ni pe won fi baalu ijagun naa lọ si agbegbe Kamadougou Yobe ni lati fi koju awon onise ibi Boko Haram ati ISWAP ko to ja.

O ni Operation Unity to jẹ iṣẹ akanṣe nibẹ gba ifitonileti pe awọn oniṣẹ ibi kan ti fẹ ṣọṣẹ ni agbegbe naa ni.

Aworan baalu to jabọ

Oríṣun àwòrán, Twitter

Báàlù ìjagun kan já lulẹ̀ ní ìlú Buhari, ẹ̀mi àwọn aráàlú bọ́

Báàlù ìjagun kan ti gbiná nílùú Buhari, ẹ̀mi àwọn aráàlú bọ́

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo lati ipinlẹ Yobe ni pe baalu ijagun kan ti ẹnikẹni kò mọ ti gbina ni abule kan to n jẹ Buhari ijọba ibilẹ Yunusari l’owurọ Ọjọbọ tó si ti pa ọpọlọpọ araalu.

Awon olugbe ilu naa sọ fún BBC awọn ti kọkọ rí baalu ijagun mẹta to n fo l’oke.

Nigba to ya, ọkan ninu wọn dede gbina lapa ibomii ninu ilu naa to sì pa eeyan oun kan ati ìdílé rẹ, araalu kan sọ fún BBC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“O ṣẹlẹ pé ni nkan bíi ago mẹjọ abọ owurọ ti ọkan lára àwọn baalu na lulẹ nibi kan ninu ilu to si gbina, gbogbo ile to wà lápá ibẹ lo jona to bajẹ.

O jẹ ọkọ baalu ijagun nla ti awon ologun ṣugbọn a o mọ pato ibi to ti wa,” o sọ fún wa.

Osojumikoro to wa níbẹ ni awọn o le sọ iye èèyàn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ bayii, “torí pé ninu ile wa nikan, a ti padanu eeyan meji bayii,” araalu yii sọ fún BBC.