Fídíò, Ẹ̀dínwó N3000 ló bá ìnáwó mi lórí ọ̀sìn ẹja nítorí afẹ́fẹ́ gáàsì CNG tí a ń lò dípò bẹntiró, Duration 5,11

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

CNG Generator: Ẹ̀dínwó N3000 ló bá ìnáwó mi lórí ọ̀sìn ẹja nítorí afẹ́fẹ́ gáàsì CNG tí a ń lò dípò bẹntiró

Awọn ọlọsin ẹja ni ilu Ilọrin ni awọn naa ti ja si lilo afẹfẹ idana gaasi dipo epo bẹntiro fun ẹr amuna wa wọn.

Gẹgẹbi ọgbẹni Paul Ọladimeji ṣe sọ fun BBC News Yoruba, ọgbọn lita epo lawọn miran maa n lo nigba miran lojumọ fun iṣẹ ọsin ẹja wọn.

Amọṣa ni kete ti owo iranwọ ti yọ kuro lori epo bẹntiro bayii lawọn ti kọ oju si lilo afẹfẹ gaasi.

Ọgbẹni Ọladimeji ni kilogiramu mejila (12kg) gaasi lawọn n lo bayii.

O ni wakati mẹjọ mẹwaa ati mejila lawọn n lo fi n pọn omi fun awọn ẹja lojumọ.

Ẹrọ amunawa yii lawọn si n lo lati fi pọn omi naa.

CNG ti mu adinku inawo ba owo ọsin ẹja wa

“Nitemi, lita epo bẹntiro mẹwaa ni mo maa n lo lojumọ. Mo ni awọn akẹgbẹ mi to n lo ọgbọn lita lojumọ. Ṣugbọn nigba ti a bẹrẹ si ni lo afẹfẹ gaasi, o dinku diẹ.

” Iru ẹni to n lo ọgbọn lita ti di ẹni to n lo gaasi kilogiramu mejila (12kg) gaasi bayii.”

O ni gbogbo awọn ọlọsin lo kọkọ bẹru lori lilo gaasi yii nitori ibẹru ijamba ina.

Amọṣa o ni lẹyin ọpọlọpọ idanilẹkọ, awọn eeyan awọn ti bẹrẹ si ni mọ bo ṣe tọ.