Alága káńṣù, Ọ̀jọ̀gbọ́n fásítì àti àwọn mìí sekúpa erin méjì,ẹyẹ àwòdì,Ìjọba pariwo síta

Aworan erin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ lorileede Naijiria ti bẹrẹ iwadii lati mọ idi ti alaga kansuu kan ati awọn ọmọ ogun Naijiria ti ṣe sẹkupa erin meji

Bẹẹ naa ni wọn l’awọn n tọ pinpin awọn eeyan kan to gbẹmi awọn ẹyẹ awodi meji kan to go lati ilẹ yuroopu wa si Naijiria.

Ipinlẹ Kebbi, Sokoto ati ipinlẹ Oyo lawọn iṣẹlẹ iṣeku pa awọn ẹranko ati ẹyẹ wọnyii ti waye.

Minisita f’ọrọ ayika Naijiria,Iziaq Salako lo sọ ọrọ yi di mimọ lasiko tó n ba awọn akọroyin sọrọ ni Abuja to si seleri pe “ileeṣẹ ayika labẹ akoso mi yoo bẹrẹ iwadii lati ri pe awọn to wa nidi ṣiṣe iku pa awọn ẹyẹ ati ẹranko yi yoo foju wina ofin.”

O ṣapejuwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi eleyi to bani ninu jẹ pẹlu bi awọn eeyan ko ṣe bikita gbigbẹmi awọn ẹranko layika wọn lalae nidi.

Alaga kansuu lo pase ki awọn ologun pa ẹrin

Ninu alaye rẹ Iziaq sọ pe awọn ologun ni Kala Balge ipinlẹ Borno lo sẹku pa erin kan nínú meji taa n wi yi.

O si ni alaga ijọba ibilẹ lo pàṣẹ ki wọn sẹku pa erin naa.

Nipa erin keji, alaye ti Minisita ṣe ni pe Ọjọgbọn fasiti kan lati ile ẹkọ fasiti Ibadan n’ipinlẹ Oyo lo pa erin keji.

Bakan naa Minisita salaye pe iroyin tun kan awọn pe awọn ẹyẹ awodi meji onírinajo lati Yuroopu to kọja ni ipinlẹ Kebbi ati Sokoto kan agbako iku lọwọ awọn eeyan kan.

O ni ” ileeṣẹ wa n gbiyanju lati ri ẹrọ transmita ti wọn so mọ awọn ẹyẹ yi lẹsẹ lati ibiti wọn tí n fo bọ wa ki a baa le da wọn pada fawọn oniwadii Yuroopu to gbe iṣẹ ran awọn ẹyẹ yi”

Salako sọ pe iru iwa yi n ṣe akoba fun ayika to sì lo yẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ wi pe o tako adehun ti Naijiria buwọlu lati fi daabo bo awọn ẹranko ati ẹyẹ lagbaye.

Ijọba ko ni faramọ iru iwa yi rara ati rara

Minisita Iziaq Salako sọ pe labẹ ofin tàwọn ati awọn orileede mii lagbaye buwọlu, ṣiṣeku pa erin ati awọn ẹyẹ awodi yi t’awọn kakun ẹranko to wa ninu ewu ko ba oju mu.

“Didẹ ọdẹ, pipa,mimu tita tabi pipa awọn ẹranko to wa ninu ewu yi jẹ ẹsẹ ti wọn lè tori rẹ wọ awọn ti ba ṣe bẹẹ lọ si ile ẹjọ”

O kilọ pe “ijọba ko ni faaye gba iru iwa buruku yi lati ọwọ ẹnikẹni tabi lati ọwọ awọn olugbe aaye kankan.Pipa tàwọn eeyan pa awọn ẹranko yi lọna aitọ safihan aibọwọ fun ẹmi awọn ẹranko”