Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta di àwátì nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní Calabar

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn akẹkọọ to to mẹrinla ni ye ni wọn salabapade ijamba ọkọ oju omi lọjọ Satide ti mẹta ninu wọn si di awati niluu Calabar to jẹ olu ilu fun ipinlé Cross Ruver.

Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Irene Ugbo lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ, to si ni awọn dola mọkanla ninu awọn akẹkọọ sugbọn awọn mẹta miiran ti di awati bayi .

Isẹlẹ naa lo waye ni dede ago mẹta ọsan lọjọ Satide lasiko ti awọn akẹkọọ n gba ifẹ ninu ọkọ oju omi ọhun.

Awọn akẹkọọ ti wọn jẹ akẹkọọ eto ilera ti wọn wa lati origun mẹrẹrin orilẹede Naijria lati kopa ninu apero NIMSA to n lọ lọwọ ni Calabar.

Ninu igbiyanju wọn lati mọ nipa ilu naa ni awọn akẹkọọ ọhun morilẹ ibi igbafẹ Marina Resort lati rin irinajo ninu ọkọ oju omi.

Gomina Bassy Otu ti ipinlẹ Cross Rivers ti palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori isẹlẹ naa.

Otu sọ eleyi ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Emmanuel Ogbeche buwọlu fun awọn akọroyin, nibi ti Gomina ti ni ẹgbẹ ọkan lo jẹ fun ohun bi wọn ko se ti sawari awọn akẹkọọ mẹta naa.

O wa rọ awọn ẹlẹsọ abo lati gbiyanju lori riri awọn akẹkọọ naa, ki wọn si pada sọdọ mọlẹbi wọn.

Bakan naa ni Gomina ni gbogbo awọn to lọwọ ninu bi ọkọ oju omi se ni ijamba ni wọn yoo foba ba ofin, ti iya to tọ yoo si jẹ wọn.

“Iroyin yii ba mi lọkan jẹ pupọ, yatọ pe mo jẹ Gomina, abiyamọ tun ni mi pẹlu.

“O yanilẹnu pe awọn eeyan to to iye naa wa ninu ọkọ oju omi, eyi to le lewu pupọ, eyi lo si fa ti fi f’e bẹrẹ iwadii wa lori pe awọn wo lo fi aye silẹ fun irufẹ isẹlẹ yii fi wa ye.

“Pupọ awọn to wa nini ọkọ oju omi ni wọn ko asọ idabobo lara.”