A mọ̀ bó ṣe ń jáa yín lára jẹ tó, a ó dá Twitter padà láipẹ́ – Ìjọba àpapọ̀

Lai

Oríṣun àwòrán, @thebridgenewsng

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti jẹjẹ lati da lilo oju opo ibaraẹnisọrọ ti orilẹede Amẹrika da silẹ pada ni Naijiria lẹ́yin to ti le ni ọgọrun ọjọ ti wọn paṣẹ pe ko kogba rẹ kuro ni Naijiria.

Ijọba jẹ ko di mimọ pe gbogbo ọrọ to fa sababi gbigbe òté lee lori lawọn ti n wa ojutu si ni lọọlọ yii to si ni ipadabọ Twitter yoo to de.

Minisita fun iroyin ati aṣa Lai Mohammed to ti n gbẹnusọ fun ijọba lori ọrọ yii naa lo tun fi aridaju eleyii han l’Ọjọbọ lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ to waye nile Aarẹ l’Abuja lasiko to n dahun ibeere awọn oniroyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ Ọgbẹni Lai kọ lati sọ pato ọjọ ti yoo ṣẹlẹ amọ o ni ifọrọjomitoro ọrọ to n waye lọwọlọwọ laarin ijọ̀ba atawọn aṣoju Twitter ti n so eso rere to si ni pe igun mejeji ti ṣetan lati fopin si ohun to ṣẹlẹ.

aworan idanimọ Twitter

Oríṣun àwòrán, other

Minisita ni “mo lero wipe Twitter gan fi atẹjade sita lori ibi ọrọ de duro nibi ijiroro wa ti mo ba si ni ki n gba ẹnu wọn sọrọ, o ti n so eso rere to si n waye pẹlu ibọwọ.

Lori pe ki n ṣapejuwe asiko ati bi yoo ṣe sunmọ to, mo fẹ fi daa yin loju pe iye akoko to ti to taa ti kogba Twitter wọle, bi a ba woo si asiko ti yo pada gberasọ, o kere jọjọ”.

O ni eyi tumọ si pe niwọn igba to j pe o ti pe ọgọrun ọjọ ti wọn ti pa aṣẹ naa, “mo lee sọ fun yin ohun ta n sọrọ rẹ yii ko le ju ọjọ bii melo kan lọ mọ”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lai Mohammed ṣalaye pe ohun tawọn n gbiyanju lati ṣe ni ayipada ṣugbọn a ni lati ṣe gbogbo rẹ lọfintoto “ṣugbọn mo lee fi da wa loju pe a mọ bo ṣe ri lara awọn ọmọ Naijiria awa igun mejeji si n ṣiṣẹ takuntakun lati fopin si ọrọ naa”.

O ni “gẹgẹ awọn aṣoju Twitter gangan naa ṣe sọ, awọn ayipada naa n so eso rere fun awa mejeeji kii ṣe ni ti ka kan gba ni nimọran rara. Ohun gbogbo si n lọ pẹlu ibọwọ”. Lai Mohammed sọ fun awọn oniroyin.