Obìnrin nipò ààrẹ Nàìjíríà tọ́ sí l’ọ́dún 2023, ẹ wo ìdí tí Emir Keffi fi sọ bẹ́ẹ̀

Tí obìnrin bá le ṣe àṣeyọrí nínú ẹbí wọn tí wọ́n sì n ṣe ìtọ́jú àwọn mọ̀lébí, wọ́n le mójútó orílẹ̀-èdè yìí

Oríṣun àwòrán, HRM Yamusa

Emir ilú Keffi Alhaji Shehu Yamusa lll ti ke si àwọn obìnrin ní Nàìjíríà láti fi ìfẹ́ hàn sí ètò ìṣèjọba pàápàá jùlọ láti dupò ààrẹ lẹ́yìn tí àarẹ Muhammadu Buhari ba kúrò nípò lọ́dún 2023.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti pa ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ́yà mẹyà, ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ń ṣe tàbí irú ẹ̀sì tí wọ́n ń sìn ti, ki wọn yọ ọrọ̀ àṣà kúrò nínú ètò òṣèlú láti rii dájí pé ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n dé ipò ààrẹ.

Ọba alayé náà to tún jẹ́ Gíwá fásiti Nasarawa ló sọ̀rọ̀ náà lónìí Ọjọ́bọ nígbà ti àwọn ẹgbẹ́ kan t n rí sí iṣẹdédé ọkùnrin àti obinrin nínú ètò òṣèlú ṣe àbẹ̀wò síi láàfin rẹ.

Lára àwọn tó ṣe àbẹ̀wò náà ni ààrẹ obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ́ lórílẹ̀-èdè Kosovo, Atifete Jahjaga.

Yamusa fi kun un pé, òun ń pe àkíyèsí gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè yìí si ọ̀rọ̀ pe àṣà àti òṣèlú kìí ṣe nǹkan kan náà.

“Ọ̀pọ̀ lo máá n fi àwọn nǹkan méjì yìí wé ara wọn, àṣìṣe ńla ni èyí, èyí sì ti mú ọ̀pọ̀ obìnrin láti má ni àǹfàni láti jáde dìbò tàbí gbé igbá ìbò, sùgbọ́n òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nibẹ̀ ni pé, ara wa ni wọ́n, ó sì yẹ kí a jọ ni àṣepọ̀.

“Pẹ̀lú ìṣèsí wọ́n nínú ilé olúkúlùkù, mó lérò pé ó yẹ kí a fún wọn ni àǹfàní nínú ìdìbò tó n bọ lọdún 2023.

” Tí obìnrin bá le ṣe àṣeyọrí nínú ẹbí wọn tí wọ́n sì n ṣe ìtọ́jú àwọn mọ̀lébí, wọ́n le mójútó orílẹ̀-èdè yìí”.

Bákan náà lo ké pe àwọn tó n wà nídi ètò òṣèlú Nàìjíríà, láti bọ̀wọ̀ fún àwọn nǹkan ti obìnrin ń ṣe ni àwùjọ àti irú àgbára tí wọ́n ni”

Ó tẹ̀síwájú láti sọ pé, àwọn obìnrin le pèsè irú ìdarí tí orílẹ̀-èdè yìí nílò níttórínà ó yẹ kí wọn ri ifọ̀wọ́sowọ́pọ̀ tó yẹ láti jáwé olúbori nínú ìdìbò ààrẹ lọ́dún 2023.