A ṣe àṣìṣe, kìí ṣe DJ Switch ni a mú – Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/SP Benjamin Hundeyin/dj_switchaholic

Ṣe lootọ ni pe Ileeṣẹ Ọlọpaa ti mu gbajugbaja oluwọde Endsars, Obianuju Catherine Udeh ti ọpọ mọ si DJ Switch saa ahamọ?

Ibeere yii ni ọpọ n bi arawọn lẹyin ti ọpọlọpọ rogbodiyan bẹ silẹ lori ayelujara.

Saaju ni Ileeṣẹ ọlọpaa kede sita pe ọwọ awọn ti tẹ ọdọbinrin naa fẹsun pe o kọlu Ọlọpaa kan.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin lo ti kọkọ fidi iroyin naa mulẹ sugbọn o pada jade sita tọrọ aforijin lọwọ oniweroyin pe a siṣe ni.

Hundeyin ni DJ Commissioner Wysei ni o wa atimọlẹ ki ṣe Dj Switch.

“Asiṣe ti wa lati ọwọ wa. Ẹni ti ọwọ wa tẹ ni DJ Commissioner Wysel ki ṣe DJ Switch.

“Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn Ileeṣẹ iroyin ti mo ti kọkọ fi di rẹ mulẹ fun wọn pe ọwọ ti tẹ DJ Switch .

“Bakan naa ni mo tọrọ aforijinlọwọ DJ Switch naa.”

Skip Twitter post, 1

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 1

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Irọ́ ni pé mo wà ní àhámọ́ Ọlọ́pàá – DJ Switch

Saaju ki agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa Benjamin Hundeyin to bọ sita lati tọrọ aforijin ni DJ Switch ti bọ sori ayelujara lati wọgile iroyin to ni o wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

O ni owurọ oni lo da bi ọjọbi oun nitori bi oun ṣe gba ipe ati atẹjisẹ kaakiri lati ọdọ awọn to fẹ mọ pe ṣe lootọ ni oun wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa.

“Orisirisi ipe ati atẹjisẹ lo jimi laarọ yii. Mo bẹrẹ si ni ma ro pe ki lo ṣẹlẹ, oni kọ ni ọjọbi mi.

“Ko pẹ lo han si mi pe wọn ni mo wa ni ahamọ Ileeṣẹ ọlọpaa.

“Koda iroyin kan ni mo kọlu Ọlọpaa. Lootọ n ko ni fẹ awọn ọlọpaa yii sugbọn mo lodi si irufẹ iwa pe ki eeyan kọlu ọlọpaa.

“Awọn akọroyin ni lati ma ṣe iwadii saaju ki wọn to gbe iroyin sita nitori o lewu pupọ.”

Skip Twitter post, 2

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 2

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

DJ ti wa sọrọ labẹ ohun ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa gbe sita nibi to ti n tọrọ aforojin pe oun ti forijin fun asiṣe naa.

Skip Twitter post, 3

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 3

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Taa ni DJ Switch?

Orukọ abisọ DJ Switch ni Obianuju Catherine Udeh, o jẹ olorin to gbegba oroke ninu idije X Factor akọkọ iru rẹ, ti ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Glo ṣagbatẹru rẹ lọdun 2013.

O jẹ ọmọ ilu Udi, ni ipinlẹ Enugu, oun si ni abikẹyin iya rẹ.

O kẹkọọ jade ninu imọ Geology ni Fasiti ijọba apapọ to wa ni ilu Port Harcourt, ni ipinlẹ Rivers.

Okiki rẹ bẹrẹ si n kan lẹyin ti oun ati ẹgbẹ rẹ Da Pulse jawe olubori ninu idije orin Star Quest lọdun 2009.

Lẹyin naa lo gbe awo orin kan jade eyii to pe akori rẹ ni “So tey,” ti olorin takasufẹ ilẹ Amẹrika, Busta Rhynes kopa ninu rẹ.

Ko pẹ si asiko naa to darapọ ileeṣẹ to n gbe orin jade, Sony Music.

DJ Switch jẹ ọkan gboogi lara awọn to n lọgun iwọde End SARS lori ayelujara.