Kò rọrùn, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣé Másà ní ẹ̀yìnkùlé ilé Baba mi -Aisha Abimbola

Arabinrin Aisha Abimbola jẹ akẹkọọ jade fasiti to kọ nipa sọrọsọrọ sugbọn to yan iṣẹ ounjẹ sise laayo.

Abimbola ko tun wa yan ounjẹ ilẹ Yoruba gẹgẹ bii ohun to ṣe fun awọn ololufẹ rẹ, Masa ni o ni oun fẹran si lati ma ṣe.

Masa jẹ ounjẹ ilẹ Arewa ni oke ọya orilẹede Naijiria,

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Abimbola salaye pe ilu Kano ni awọn obi oun bi oun si ko to pe wọn gbera pada wa si ilu Ilorin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.

Aworan

O ni nitori pe oun fẹ da yatọ ninu awọn olopo yooku to n ṣe ounjẹ bi tiẹ ni oun fi yan siṣe Masa laayo gẹgẹ bii iṣẹ.

“Igba ti mo fẹ bẹrẹ ounjẹ tita, mo ri pe awọn eeyan lati Arewa, wọn maa n fẹran eeyan to mọ ounjẹ wọn ṣe daadaa.

“Emi dẹkẹ ree, ibẹ ni wọn bi mi s, ti mo si mọ ounjẹ naa ṣe.”

Abimbola tẹsiwaju pe ilọsiwaju de ba okowo rẹ nipasẹ iranlọwọ ti awọn mọlẹbi rẹ ṣe fun lasiko to fẹ siṣe okowo naa.

“Nigba ti mo bẹrẹ ko rọnu rara, Kanda ti awọn Hausa maa fi n ṣe Masa ni mo fi bẹrẹ

“Koda, ẹyin ile wa ni mo n lọ pẹlu eedu ati adogan ibilẹ, nigba to ya ni awọn mọlẹbi mi bu mi ni owo diẹ ti mo fi ra eyio ti mo n lo lọwọ nisin yii.”

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí