Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin aláìsaǹ ‘sickle cell’ tó ṣáré kìlómítà mẹ́wàá

Obinrin ọmọ orilẹ-ede Kenya kan to ni aisan foniku-fọladide ‘sickle cell’ ti ṣalaye bo ṣe n doju ija kọ aisan naa.

Obinrin ọhun, Lea, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, sọ pe oju ẹni ti yoo ku laipẹ ni wọn fi n wo ẹnikẹni to ba ni arun naa lorilẹ-ede awọn.

Bo tilẹ jẹ pe pupọ ninu awọn ọmọde to ni aisan naa lo n ku ki wọn to pe ọdun marun un ni Kenya, Lea ṣi wa laaye.

Lea

Lara igbiyanju rẹ lati fi han faraye pe awọn to ba ni aisan ‘sickle cell’ naa ṣi le gbe igbeaye to dara, o darapọ mọ awọn to n kopa ninu ere ije oni kilomita mẹwaa to waye nilẹ naa.

Ninu alaye rẹ fun BBC, o ni awọn dokita gba oun nimọran lati maṣe kopa ninu ere ije naa amọ oun kọ jalẹ nitori oun ti pinnu lati ṣe bẹẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, nnkan bii ida mẹrin awọn eeyan agbegbe to ti wa, iyẹn ni Taveta, lo n ba aisan foniku-fọladide ‘sickle cell’ fnaa inra.

Igbagbọ awọn eeyan naa ni pe iṣẹ ayẹ ati awọn ajẹ ni aisan naa jẹ.

Lẹyinorẹyin, o kopa ninu idije naa, amọ o daku rọgbọndan nigba ti yoo pari rẹ.

Ni bayii, Lea ti fi ara rẹ jin lati maa ṣe ipolongo ati ilanilọyẹ nipa aisan ‘sickle cell’ ọhun.