Ọkọ̀ ojú omi dànù ní ìpínlẹ̀ Kwara, ẹ̀mi èèyàn 150 sọnù

Kwara boat accident

Oríṣun àwòrán, @DonaldRex

Ijamba ọkọ oju omi kan to waye niluu Patigi, nipinlẹ Kwara ti mu ẹmi aadọjọ eeyan lọ.

Iroyin ni asiko ti awọn eeyan naa n bọ lati ibi ayẹyẹ kan ni ijamba ọkọ oju omi ọhun waye.

Emir ilu Patigi, Alhaji Ibrahim Umar Bologi ṣalaye fun awọn akọroyin pe nnkan bii ọọdunrun eeyan lo wa ninu ọkọ oju omi naa lasiko to da oju de.

Yatọ si awọn to ku, Emir naa sọ pe awọn ti doola, o kere tan, eeyan mẹtalelaadọta.

O fi ku pe isẹ ti n lọ lọwọ lati yọ awọn oku to ṣeku sinu odo ti ọkọ naa danu si.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Nigba to n ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, Emir ọhun sọ pe “nnkan bii aago mẹta oru ijẹta ni iṣẹlẹ naa waye.”

“Gẹgẹ bii iroyin ti a gbọ, ẹrọ ọkọ oju omi naa ti nnkan bii ọọdunrun eeyan wa ninu rẹ lo ṣadede kọṣẹ.”

“A ti bẹrẹ si n ṣe ilanilọyẹ fun awọn eeyan wa bayii lati mọ iye ero to yẹ ko wa ninu ọkọ oju omi lẹẹkan ṣoṣo, a tun n rọ ijọba ki wọn fun wa ni awọn aṣọ to le mu eeyan lefo sori omi.”

Ijọba Kwara kẹdun awọn to jade laye

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ba awọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lẹyin iṣẹlẹ laabi yii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina AbdulRahman AbdulRazaq, iyẹn rafiu Akajaye fi lede, o ni iṣẹlẹ naa ba ijọba ninu jẹ gidi.

O ni “Inu gomina bajẹ gidi nipa ijamba ọkọ oju omi to danu eyii ti ọpọ eeyan wa ninu rẹ, paapaa awọn eeyan Ebu, Dzakan, Kpada, Kuchalu, ati Sampi, ti gbogbo wọn jẹ eeyan Patigi.”

“Gomina ba awọn eeyan agbegbe ọhun kẹdun, to fi mọ awọn mii ti ọrọ naa kan lati ipinlẹ miran.”