Wo kókó ọ̀rọ̀ mẹ́fà tí Buhari sọ àti àǹfàní tí àtúnṣe owó náírà yóò mú bá Nàìjíríà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN lati da 200 naira pada fun awọn araalu lati na.

Buhari fi lede lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni aarọ Ọjọbọ, Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Keji, ọdun 2023.

O paṣẹ fun CBN lati jẹ ki 200 naira ti atijọ jẹ ohun ti awọn eniyan yoo maa na kaakiri orilẹede Naijiria fun ọgọta ọjọ ki o to di ohun afiṣẹyin.

200 naira ti tẹ́lẹ̀ nìkan ní ẹ lè ná, ẹ kò leè ná 500, 1000 mọ́! – Ààrẹ Buhari

”Ẹ le na 200 naira lati February 10 si April 10, 2023 ki a to fopin si owo naa.

Amọ aarẹ Buhari ni 500 naira, 1000 naira ti atijọ ni Naijiria ti di ohun igbagbe ni Naijiria.

‘’Mo paṣẹ fun CBN lati gba 200 naira laaye, amọ CBN nikan lo lee gba 500, 1000 naira ti atijọ pada’’

Awọn nkan miran ti aarẹ sọ fun awọn ọmọ Naijiria ree…

Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ ma binu lori ọwọngogo owo Naira to gbode

Aarẹ Muhammadu Buhari lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ tọrọ aforiji lọwọ wọn nipa ọwọngogo owo naira to gbode kan.

Buhari ni idi ti awọn fi gbe igbeṣẹ naa ni lati fopin si eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

Aarẹ Buhari ni awọn woye pe atunṣe owo naira naa yoo fopin si eto aabo to dẹnukọlẹ to fi mọ ijinigbe to peleke si nitori awọn to n san owo ẹmi fun awọn ajinigbe lati doola ẹmi awọn eniyan wọn.

Bakan naa ni aarẹ fikun pe awọn jẹgudujẹra to ko owo pamọ sile, ko ni lee ri lo, paapaa awọn ọbayejẹ to n lu owo ilu ni ponpo, ti wọn si n ko pamọ si ile wọn.

Aarẹ Buhari ṣalaye anfaani ti atunse owo naira yoo mu ba Naijria.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

  • Aarẹ Buhari ni laarin oṣu melo ti ijọba ti gbe igbeṣẹ lori owo naira ni awọn ayipada kọọkan ti waye ni ẹka ọrọ aje ati bẹẹ lọ.
  • Buhari ni iye owo ti awọn eniyan ni ni ipamọ ti ko si ni banki ni ọdun 2015 jẹ 1.4 trillion naira ti o si wọ 3.25 trillion naira ni ọdun 2022, eyi to ṣafihan bi awọn eniyan ṣe n ko owo pamọ.
  • ”Amọ ni bayii, awọn eniyan ti da iye owo to le ni trillion meji pada si banki.
  • Nibayii, awọn olokowo kekeeke yoo ni anfaani lati yawo, ti iye owo ori rẹ yoo si jẹ perete.
  • Bakan naa ni iwa ajẹbanu yoo dinku, ti ọwọngogo ounjẹ yoo si dopin.
  • Aarẹ Buhari fikun un pe iye owo naira si iye owo ilẹ okeere yoo wa loju kan, ko ni maa goke si lojoojumọ.

Awọn ọna abayọ tuntun ti aarẹ Buhari kede lori atunse owo Naira…

Aworan

Oríṣun àwòrán, Buhari/ Twitter

  • Aarẹ Buhari ṣalaye awọn ọna abayọ tuntun si ọwọngogo owo naira to gbode kan.
  • O ni lẹyin ọpọlọpọ ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ lọna ati mu idẹrun ba awọn araalu, ki rogbodiyan to bẹ silẹ le dopin.
  • Aarẹ ni oun ti paṣẹ fun CBN lati wa ọna abayọ si ọrọ awọn ọbayejẹ to fa ọwọngogo owo tuntun naira naa.
  • ”Mo ti paṣẹ fun CBN lati la awọn eniyan lọyẹ lori idi ti atunṣe fi ba owo naira.”
  • ”Ki awọn ẹsọ alaabo ṣawari awọn ọbayejẹ to ko owo naira pamọ, ti wọn si fi oju wina ofin”
  • ”Ki awọn banki fun awọn eniyan ni 200 naira atijọ ki owo le wa fun awọn eniyan”
  • ”Bakan naa ni ki wọn maa fun awọn eniyan ni 200 naira, 500 naira ati 1000 naira tuntun amọ wọn ko le gba owo titẹlẹ lọwọ wọn.”
  • Ọgọta ọjọ ni wọn yoo fi na owo atijọ naa lati Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Keji, ọdun 2023 si Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kẹrin, ọdun 2023, ki o to lukudeeti.

”Ẹ bọ sita ni ọjọ idibo ki ẹ dibo fun aarẹ ti ọkan yin fẹ”

Aarẹ Buhari ti ni idibo sipo aarẹ yoo waye ni Ọjọ Karundinlogbọn, Oṣu keji, ọdun 2023.

Eyi wa lara awọn idibo ti yoo waye ni idibo gbogboogbo ti ọdun 2023.

Aarẹ Buhari wa kesi awọn eniyan lati tu jade lọgọọrọ lati dibo fun ẹni to wu wọn gẹgẹ bi aarẹ lasiko idibo naa.

Ààrẹ Buhari bá àwọn ọmọ Naijiria sọ̀rọ̀ ní 7am láàrọ̀ òní lórí bí ó ṣe ń lọ ní Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe oun yoo ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni aago meje owurọ Ọjọbọ.

Eyi ko ṣẹyin rogbodiyan to bẹ silẹ kaakiri orilẹede Niajiria lẹyin gbedeke owo tuntun naira.

Ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina fi lede ni aarẹ ti kede igbeṣẹ yii.

Wọn kesi awọn ileeṣẹ radio ati tẹlifisọn lati darapọ mọ NTA fun igbohunsafẹfẹ aarẹ Buhari naa.

O ṣeeṣe ki igbohunsafẹfẹ aarẹ naa niiṣe pẹlu owo Naira tuntun ati awọn iṣẹlẹ to ti waye nitori rẹ.

Bakan naa ni idibo n bọ lọna, ti ko si ju nkan bi ọṣẹ kan lọ mọ si isinyii.