Mo mọ ohun tí ẹ̀ ń là kọjá lórí ọ̀wọ́ngógó nàírà – Oyetola sí àwọn ará Osun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti ba awọn araalu kẹdun lori ọwọngogo owo naira to gbode kan.

Oyetola lo ba awọn oniroyin sọrọ to si ni oun ni imọlara inira ti wọn n la kọja ati iya ati iṣẹ ti aisi owo naa ti fa.

O ni asiko diẹ si isinyin ni opin yoo de ba ohun ti wọn n la kọja.

Oyetola to jẹ adari eto ipolongo sipo aarẹ nipinlẹ Osun fun ẹgbẹ oṣelu APC lo sọrọ tako bi awọn onijagidijagan ṣe n ṣekọlu si ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa.

‘’A ti sọ fun ijọba ki wọn ma fi aye ni awọn araalu lara nitori ọrọ oṣelu ‘’

Oyetola to sọrọ saaju aarẹ Buhari ni ki awọn eniyan fi ọkan balẹ nitori ohun gbogbo to le n gbọ wa di ẹrọ.

Bakan naa lo ni ki wọn tẹlẹ aṣẹ ileẹjọ giga julọ lorilẹede Naijiria lati maa na owo atijọ naa

Gomina naa wa rọ awọn eniyan lati duro de aṣẹ ileẹjọ to gajulọ ni Naijiria fun ọna abayọ si ọrọ ọwọngogo owo naa.

‘’Ẹgbẹ oṣelu APC ko faramọ iya ati iṣẹ ti awọn eniyan n la kọja nitori aisi owo naa.’’

‘’Awa ti sọ fun ijọba apapọ pe ki wọn ma fi ẹmi awọn eniyan wewu nitori ọrọ oṣelu.’’

‘’A rọ yin ki ẹ jade dibo ni Ọjọ Karundinlọgbọn oṣu yii, ki ẹ si gba alaafia laaye

Ìgboro ti dàrú ní Ibadan àti Ilorin torí ọ̀wọ́ngógó owó náírà tuntun!

New naira notes

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii bayii ni awọn olu ilu awọn ipinlẹ kọọkan ti n foju wina ifẹhonuhan latari aisi owo naira tuntun ati epo bẹntiro ni Naijiria.

Ninu alaye ti awọn akọroyin BBC Yoruba to lọ kaakiri ṣe, ṣe ni gbogbo ọna di fọfọ ni Ibadan ti sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ si ti bẹ silẹ, eyi to fa idiwọ fun awọn akọroyin gaan lati de ibi to ti n waye.

Eyii ko sẹyin bi awọn araalu kan ṣe ko awọn taya ọkọ lati fi di oju popo.

Lara awọn agbegbe ti iwọde naa ti milẹ titi julọ niluu Ibadan ni Eleyele, Gbopa, Ologuneru, Apete, sango, Poly road, Mokola ati Iwo Road.

New naira notes

Awọn ọdọ naa gbe igi di awọn opopona kakiri ilu Ibadan, eyiit to fa idiwọ fun gbogbo awọn ti wọn n kọja.

Wọn tun ṣeleri lati tẹsiwaju ninu ifẹhonuhan ọhun titi ti ijọba yo fi wa ojutu si aito owo naira tuntun.

Ni ilu Ilorin, awọn araalu dana sun taya ladugbo Ipata Oloje lati fi ẹhonu wọn han si ọwọngogo naira.

Akọroyin BBC Yoruba ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ jabọ pe eredi ifẹhonuhan ọhun ko ṣẹyin bi awọn eeyan naa ko ṣe ri owo naira tuntun na, nigba ti awọn araalu tun n kọ owo naira atijọ.

“Ebi n pa wa”

Lara awọn araalu to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe ebi ti bẹrẹ si n pa wọn bayii nitori wọn ko le fi owo ọwọ wọn ra ounjẹ.

Baba agbalagba ka ti ko darukọ rẹ sọ fun BBC pe “Ẹdakun, ebi n pa wa.”

“Ti a ba fẹ ra ounjẹ, wọn ko gba owo atijọ lọwọ wa mọ, ẹ ba wa bẹ ijọba ki wọn ṣaanu fun wa.”

Baba agba naa wa rọ ijọba lati ko owo naira tuntun sita tabi ki wọn fi ọjọ kun gbedeke iye ọjọ ti wọn yoo ko owo atijọ wọle.

“Mi o tii jẹun lataarọ”

Iya agba mii to tun ba BBC Yoruba sọrọ niluu Ilorin, Nafisatu sọ pe, awọn n fẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si ọrọ ọwọngogo owo naa.

O ni “Mi o tii jẹun aarọ bi mo ṣe wa yii, mọ mu owo lọ sibi ti mo ti fẹ ra ounjẹ, wọn ko gba lọwọ mi.”

“Ọmọ mi fẹ fi owo ranṣe ranṣẹ si mi, mo de ibi ti mo ti fẹ gba owo wọn ni ko si owo, niṣe ni mo pada wale.”

Lẹyin naa lo ke si ijọba lati wa ojutu si iṣoro ọwọngogo owo naa.

Ẹwẹ, awọn araalu ko ba dukia kankan jẹ niluu Iloprin lasiko iwọde ọhun gẹgẹ bii akọroyin wa ṣe jabọ.