Wo ẹni tí yóò di gómìnà lẹ́yìn ikú Akeredolu, àti ohun tí òfin sọ nípa rẹ̀

Aworan Akeredolu ati Igbakeji rẹ Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi/

Kii ṣe iroyin tuntun mọ wi pe Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu ti papoda.

Idagbere faye rẹ tunmọ si pe oun naa darapọ mọ awọn Gomina to dipo mu sẹyin ni ondo to ti dagbere faye.

Oluegun Mimiko nikan lo ṣẹku bayii laye ninu awọn gomina alagbada to ti jẹ ni ipinlẹ naa.

Akeredolu ti lọ bẹẹ si ni iṣejọba ko duro.

Ki wa lo kan bayii ti ẹni to di ipo Gomina mu nipinlẹ yi ti lọ?

Ki ni ohun ti ofin orileede Naijiria sọ nipa itẹsiwaju iṣejọba?

Ohun ti onimọ ofin ṣalaye fun BBC ree:

Agbara ti pada sọdọ iwe ofin orileede Naijiria

Aworan Gomina ati igbakeji ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Agbẹjọro Solihu Adebayo to fi ilu Ibadan ṣe ibujoko ṣalaye fun BBC pe ohun to bani lọkan jẹ ni ki Gomina papoda lasiko to wa lori oye amọ bo ba ti waye bẹẹ o ni ilana ti iwe ofin la kalẹ.

O sọ pe labẹ ofin Naijiria ipapoda Gomina tabi aarẹ a maa ṣi aye silẹ fun ki igbakeji rẹ bọ si ori ipo naa.

‘’Igbakeji Gomina yoo kede iku Gomina ti yoo si dajọ ti wọn yoo fi ṣe idaro rẹ ni ipinlẹ naa’’

Gbogbo eleyi a maa waye pẹlu bi wọn yoo ṣe mu asia orileede walẹ ni idaro ẹni to papoda.

‘’Ko si ṣiṣe ko si aiṣe ju ki wọn kọkọ burawọle sipo fun igbakeji aarẹ tabi Gomina.Idi ni pe wọn ko le fi alafo silẹ ni iṣejọba bo ti le wu ko kere mọ’’

O sọ pe abala ofin to faaye gba eleyi ni abala 191 ti iwe ofin orileede Naijiria to sọ pe

‘’Igbakeji Gomina yoo dipo Gomina mu ti Gomina ko ba si ni ipo naa latari iku,ikọwefiposilẹ,yiyọ nipo tabi aiuni ikapa lati ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi Gomina.’’

Lafikun, to ba ṣe pe gbogbo idiwọ taa ka silẹ ba deba igbakeji Gomina naa, ẹni ti yoo kan labẹ ofin lati di ipo Gomina mu ni olori ile aṣofin ipinlẹ.

Ni ti orileede, aarẹ ile aṣofin agba ni wọn yoo yan sipo aarẹ to ba ṣepe ijamba to mu ẹmi Aarẹ ati igbakeji rẹ waye.

Onimọ ofin yi sọ pe gbogbo agbara to ba ipo Gomina wa si ni wọn yoo gbe le igbakeji rẹ lọwọ kete ti iburasipo yi ba ti waye.

‘’Inu mi dun pe igbakeji rẹ naa lo ti n ṣe akoso ni ipo adele.Ko ni nira lati yi ipo rẹ pada si ipo Gomina lae si idiwọ kankan.’’

Ki ni yoo ṣẹlẹ si ipo Igbakeji Gomina

Ṣaaju ni pe saa ti Gomina ati igbakeji rẹ n ṣe lọ ni ẹni ba gba ipo Gomina bayii yoo pari labẹ ofin.

Ni ti ipinlẹ Ondo, ọdun 2025 ni saa Akeredolu ati igbakeji rẹ Lucky Aqiyedatiwa yoo pari.

Bi o ba pari saa yi to si wu lọkan, igbalaye wa fun Aiyedatiwa lati tun dije dupo Gomina lẹẹkan si.

Nipa ọrọ igbakeji Gomina ti yoo maa ba Gomina tuntun ṣe ijọba saa to ku, agbẹjọro Salihu Adebayo ṣalaye pe ẹni to ba wu Gomina lo le yan sipo gẹgẹ bi igbakeji rẹ.

‘’Ẹni naa ko ni lati jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Gomina tuntun.Koda ti kii ba ṣe oloṣelu lẹni to yan, ko saburu nibẹ.Bo jẹ ọkunrin tabi obinrin, gbogbo agbara ni iwe ofin gbe le Gomina tabi aarẹ lọwọ lati yan ẹni to ba wu gẹgẹ bi igbakeji.’’

Nigba taa beere pe laarin igba wo ni iburawọle Gomina tuntun yoo waye, o sọ pe kii ṣe nkan to yẹ ko pẹ rara.

”Koda o ṣeeṣe ki wọn ti maa mura lati burawọle sipo fun bayii. O ku si ọwọ igbakeji Gomina to fẹ gba ipo ati adajọ agba ipinlẹ lati yanju bi wọn ba ṣe fẹ ko ya si.’’