Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Rotimi Akeredolu, àgbàọ̀jẹ̀ Amòfin tó dipò Gómìnà Ondo mú títí tó fí jáde láyé

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Ko si ẹni to waye ti ko ni ku.

Rotimi Akeredolu Gomina ipinlẹ Ondo ti jade laye lẹyin aarẹ toti n ba finra fun igba diẹ.

LỌjọru ni Rotimi Akeredolu jade laye ni ipinlẹ Eko nibi to ti n gba itọju.

Ohun ni Gomina ipinlẹ iwọ oorun Naijiria keji ti yoo ku lori oye.

Ninu itan oloṣelu Naijiria awọn eeyan ko ni gbagbe Rotimi Akeredolu to jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro agba to si tun jẹ gbajugbaja oloṣelu ni Naijiria.

O fi iyawo ati awọn ọmọ silẹ lọ.

Ibi ati igba ewe rẹ

Ọdun 1956 ni wọn bi Oluwarotimi Odunayo Akeredolu to si jẹ ọmọ ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.

Arakunrin ni inagijẹ rẹ ti ọpọ a maa fi pe paapa lagbo oṣelu ipinlẹ Ondo nibi to ti jẹ Gomina fun saa ẹmeeji ọtọọtọ.

Ile ẹkọ ibẹrẹ Government School lo ti bẹrẹ ẹkọ rẹ to si tẹsiwaju lati ibẹ lọ si St Aquinas College, Loyola College ni Ibadan ati Comprehensive High School Aiyetoro nibi to ti gba sabuke ile ẹkọ girama.

FasitiObafemi Awolowo ni Ile Ife lo ti kẹkọ nipa imọ ofin to sipari ẹkọ rẹ lọdun 1977.

Ọdun 1978 ni wọn pe si ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede Naijiria.

Rotimi Akeredolu, agbẹjọro ati oloṣelu ilumọọka

Aworan Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Idi iṣẹ agbẹjọro yi lo ti di ilumọọka to si pada de ipo agbẹjọro agba iyẹn Senior Advocate of Nigeria,SAN lọdun 1998.

Laarin ọdun 2008-2010 o jẹ alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro Naijiria.

Lasiko to wa lori ipo yi lo sọrọ nipa ipo ilera aarẹ Naijiria tẹlẹ Umaru Musa Yar’Adua to si ni o yẹ ki Yar”Adua gbe ijọba kalẹ fun igbakeji rẹ tori pe ko le maa ṣe ijọba nipo ailera.

Ọrọ ṣiṣe ijọba niupo ailera yi yoo pada wa kan Akeredolu naa to kọ lati fi ipo silẹ fun igbakeji rẹ nigba ti aarẹ de kaṣan ara rẹ mọlẹ.

Lara ipo ti Akeredolu tun dimu nipa iṣẹ imọ ofin ni ti Agbẹjọro agba ati Kmiṣana feto idajọ ni ipinlẹ Ondo laarin ọdun 1997 si ọdun 1999.

Lọdun 2012, ẹgbẹ awọn agbẹjọro ṣe ayẹsi rẹ nipa fifi olu ileeṣẹ wọn lAbuja peri Akeredolu fun ipa ribi to ko nipa idagbasoke ọrọ imọ ofin ni Naijiiria.

Akeredolu gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ondo

Aworan Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Ọdun 2011 ni Akeredolu pẹlu awọn oludije to dije tikẹẹti labẹ aṣia ẹgbẹ Action Congress of Nigeria lati ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo Gomina.

Lọdun 2012, wọn dibo yan ninu idibo abẹnu ẹgbẹ to si koju Olusegun Mimiko ninu idibo Gomina.

Mimiko fidi rẹ rẹmi ṣugbọn o pada sagbo oṣelu to si tun dije ipo lọdun 2016.

Ni 2016 taa n wi yi, o ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti aarẹ Bola Tinubu ti wọn si gbe asia ẹgbẹ le lọwọ lati dije ipo Gomina lorukọ ẹgbẹ naa.

Inec kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori ninu idibo lẹyin to fẹyin Eyitayo Jegede ati Olusola Oke nalẹ.

Wọn bura wọle fun sipo Gomina fun saa akọkọ lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun 2017.

Ohun ati Agboola Ajayi ni wọn jijọ wọle gẹgẹ bi Gomina ati igbakeji botilẹ jẹ wi pe ija yoo pada tu awọn mejeeji ka ki saa wọn to pari.

Nigba ti yoo fi dije dupo ni saa ẹlẹẹkeji, o ti yan Lucky Aiyedatiwa gẹgẹ bi igbakeji ti wọn si jijọ jaweolubori ninu idibo ọdun 2020.

Ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun 2021 ni wọn bura wọle fun wọn ti saa ẹlẹẹkeji si bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Ori saa ẹlẹẹkeji yi ni Akeredolu ti pari irinajo rẹ gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Ondo.

Ohun Manigbagbe nipa rẹ gẹge bi Gomina

Aworan Akeredolu ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, rotimiaketi

Eeyan ki i wa ko ma ni awọn ti nifẹ rẹ ati awọn ti wọn ko fẹ ri imi rẹ laatan.

Iha ti ọrọ Akeredolu kọ si awọn kan, ọtọ ni bo ṣe ri lọdọ awọn ẹlomiran.

Lọdọ awọn ọmọ Yoruba ni paapa wọn ri Akeredolu gẹgẹ bi Gomina kan to gbajumọ itẹsiwaju ilẹ Yoruba.

Ni paapa ọrọ aabo ati alaafia ilẹ Yoruba, a ri apẹrẹ akitiyan Akeredolu nigba to lewaju nibi idasilẹ ikọ aabo Amotekun.

Yatọ si eleyi, o wa lara awọn to tako ọrọ ikọlu gbogbo igba to n waye laarin awọn darandaran ati agbẹ nilẹ Yoruba eyi to jẹ ko tako igbesẹ ijọba apapọ to ni awọn yoo mu lara ilẹ ipinlẹ kọọkan lati fi da aaye tawọn darandaran yoo maa fi sin maalu.

Ninu awọn eeyan taa le tọka si pe Gomina Akeredolu gbena woju rẹ nipa bibeere ẹtọ to yẹ labẹ ofin fun awọn ijọba ipinlẹ ni minisita feto idajọ Abubakar Malami to di ipo mu labẹ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari.

Lọpọ igba ni Akeredolu a maa fi imọ ofin to ni tako igbesẹ to ba tako ofin Naijiria ti Malami ba n gbe.

Nidi ipo Gomina o jẹ eeyan kan to ja fita pe ki ipo aarẹ Naijiria wa si apa Guusu orileede Naijiria ti ko si sinmi lori akitiyan yi titi ti ipo naa fi ja mọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lọwọ.

Ni igbẹhin aye rẹ, awuyewuye ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ondo lori ọrọ ilera Akeredolu ati fifi ipo silẹ fun igbakeji rẹ Lucky Aiyedatiwa lati maa ṣakoso ijọba.

Wọn fa ọrọ naa titi ti aarẹ Tinubu to pada wa dasi to si ni ki Aiyedatiwa maa ba ijọba lọ gẹgẹ bi adele Gomina titi ti ara Akeredolu yoo fi bọ pada sipo.

A gbọ pe awọn mọlẹbi Akeredolu fẹ gbe lọ si ilẹ okere fun itọju amọ eyi ko pada waye.

O jade laye nile iwosan kan nipinlẹ Eko lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2022.