Wo bí wọ́n ṣe yọ́lẹ̀ gbé Nnamdi Kanu wọ inú ilé ẹjọ́ l’Abuja

Nnamdi Kanu

Gbogbo ọna to lọ si ile ẹjọ giga ti ilu Abuja ni wọn ti di gbagba pẹlu bi awọn agbofinro ṣe wa nibẹ lati mojuto ọrọ abo nibi igbẹjọ ajijagbara fun Biafra, Nnamdi Kanu.

Ọpọlọpọ agbẹjọro lawọn ọlọpaa o jẹ ki wọ́n wọ inu ọgba ile ẹjọ naa.

Amọ iroyin ni ṣe ni wọn yọlẹ gbe Nnamdi Kanu wọle si ile ẹjọ ti awn eeyan dii ni waju ati lẹyin.

Nnamdi Kanu

Ijọba Naijiria ṣe atunṣe awọn ẹsun ti wọn fi kan an wọn si tun ko awn tuntun mii jade amọ ti wọn o tii fihan ni gbangba.

Ajijagbara yii la gbọ pe ijọba orileede Naijiria fi ẹsun igbesunmmi ati iditẹgbajọba kan an.

Bi wọn ba fi le da lẹbi ẹsun yii, ẹwọn gbere ni ijiya ti yoo jẹ ipin rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ti ṣe diẹ ti Nanamdi Kanu ti wa lahamọ lọdọ awọn ikọ ọtẹlmuyẹ DSS Naijiria gẹgẹ bi awọn agbẹjọro rẹẹ ti ṣe sọ.

Lọsẹ to kọja ni ijọba Naijiria mu iyipada ba awọn ẹsun ti wọn fi kan an ti wọn si tun sọ pe o lọwọ ninu ṣiṣe akoso ileeṣẹ to lodi ofin.

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe o lọwọ ninu titẹ awọn iwe ti ọrọ inu rẹ n bani lorukọ jẹ.

Awọn agbẹjọro rẹ ti ni ki ijọba ri wi pe wọn gbe Nnamdi Kanu wa si ileẹjọ lỌjọbi tii ṣe oni.

Boya yoo yọju tabi ko ni yọju, ipade di ileẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Niṣe ni ọkan awọn eeyan ko balẹ nigba ti awọn alaṣẹ ko gbe wa sile ẹjọ loṣu Keje lati wa jẹjọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, ikọlu ati iwa janduku orisirisi lo n waye ni ilẹ Igbo lati igba ti ijọba ti mu Kanu pada.

Koda,ni ọjọ Iṣẹgun to kọja yi awọn agbebọn kan pa ori ade meji nibi ipade awọn lọba lọba.

Oṣu Kẹwa ọdun 2015 ni wọn kọkọ mu Kanu ṣugbọn o sa ni Naijiria lọdun 2017 nigba ti awọn ọmọ ogun Naijiria yabo ile rẹ.

Idibo to n bọ lọna ni Anambra jẹ ọkan lara awọn nkan tawọn araalu n jaya si.

Pẹlu ikọlu ati iwa janduku eyi to ṣokunfa iku ọpọ awọn araalu ati agbofinro, ko si ẹni to le sọ boya idibo yi yoo waye lalaafia.