Wo bí Ooni ti Ile-Ife, Pásítọ̀ Sam Adeyemi, Woli Agba, Falz, Mr Macaroni, Tiwa Savage ṣe ṣe àyájọ́ Endsars!

Endsars

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn eekan lorilẹede Naijiria lori ẹrọ ayelujara lo fi ero wọn han lori ayajọ ifẹhonuhan Endsars to waye lọdun to kọja.

Ọpọlọpọ aworan ni wọn n fi lede lati ṣeranti bi iwọde naa ṣe lọ ni ọdun to kọja.

Wọn fikun un pe awọn ko lee gbagbe lai lai ẹmi to lọ ninu iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu ọrọ tirẹ, Ọọni ti Ile Ife ni ọjọ ayajọ EndSars lorilẹede Naijiria jẹ ọjọ manigbagbẹ ni itan orilẹede Naijiria nitori o jẹ iṣẹlẹ kan patọ to mu ki awọn ọdọ lorilẹede Naijiria parapọ lati ja fun ẹtọ wọn.

Ọọni ni awọn ọdọ naa bẹrẹ fun iṣejọba to dara, ẹtọ araalu to fi mọ ijọba ti ko ni fi ẹtọ araalu dun wọn.

Endsars

Oríṣun àwòrán, Instagram

Pasitọ Sam Adeyemi ninu arọwa si awọn ọdọ ni ọjọ ayajọ Endsars ni ki awọn ọdọ Naijiria ri ara wọn gẹgẹ bi ọdọ to ni Niajiria ni ọjọ ọla.

Pasitọ Adeyemi ni ki wọn gbaradi fun iṣẹ to wa ninu iwaju wọn, ki wọn si tunbọ ma a pe akiyesi wọn si awọn ohun ti ko ba dara tọ ni ijọbs Naijiria.

O gbadura pe igbiyanju wọn ko ni jasi asan.

Endsars

Oríṣun àwòrán, Instagram

Bakan naa ni gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Woli Agba naa fi fidio lede to sọ wi pe awọn ko ni gbagbẹ gbogbo awọn ti ẹmi wọn sọnu ni ikọlu ti awọn soja ṣe si awọn afẹhonuhan Endsars ni ọdun to kọja.

Wọn kesi si ijọba pe awọn to yẹ ki wọn ma a da abo bo awọn ọdọ ni wọn tun n ṣe ikọlu si wọn.

Gbajugbaja olorin takasufe naa, Tiwa Savage naa fi awo orin sita ti wọn ti n bere ibeere pe tani o fun awọn soja ni aṣẹ lati lọ doju ibọn kọ awọn ọmọ Naijiria ni Lekki Tollgate.

Tiwa Savage ninu orin naa ni awọn ko ni gbagbe lailai nitori awọn ọdọ yii fi ẹmi wọn silẹ lati beere fun ẹtọ wọn.

Bakan naa ni gbajugbaja olorin takasufe, Folarin Falana ti ọpọ eeyan mọ si Falz to fi mọ Mr Macaroni, Charley Boy ni awọn ko ni gbagbe gbogbo awọn to ku ni Lekki Tollgate ti ijọba ko naani wọn.

Bakan naa ni wọn ni ko si nkan ti ijọba le ṣe fun wọn loni ayajọ ọjọ ifẹhonuhan Endsars nitori awọn ko pa eniyan kankan.

Bẹẹ si ni wọn bọ sita ni iye wọn pẹlu ọkọ wọn ti wọn si n tẹ ”horn” ọkọ wọn.

End SARS
Charly Boy

Awọn ọdọ miran tilẹ kọ orukọ awọn to ba iṣẹlẹ iwọde naa lọ ni ọdun to kọja, ti wọn si n sọ wi pe awọn ko le gbagbe wọn.

Amọ titi di asiko yii ijọba ṣi n sọ wi pe ko si ẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa, ti awọn soja naa ni awọn ko yin ibọn to le e pa eniyan, wi pe ”Rubber Bullet” ni wọn yin.