Ọkùnrin kan dáná sun ìyàwó àti àwọn ọmọ mọ inú ilé ní Kwara

Ilé àjókù

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE

Arákùnrin kan tó ń gbé ni òpópónà Lekki Phase 1 ní agbègbè Eyenkorin, ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara ti dáná sun ilé ìgbé rẹ̀ nítorí aáwọ̀ tó wáyé láàárín òun àti ìyàwó rẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹta, oṣù Keje, ọdún 2022 ni adarí ẹ̀ka ìpolongo àjọ tó ń mójútó ìjàmbá iná ní ìpínlẹ̀ Kwara, Hassan Adekunle fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Adekunle ṣàlàyé fún BBC News Yorùbá wí pé ní nǹkan bí ago mẹ́wàá àbọ̀ ni ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kola pe àwọn wí pé ilé kan ń jó ní agbègbè náà.

Ó ní lọ́gán tí àwọn dé ibi ilé náà ni àwọn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ri dájú pé ilé náà kò jó ju bó ṣe yẹ lọ àti pé kò fò lọ bá ilé mìíràn.

Ó ní nígbà tí àwọn wádìí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá iná náà, àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ọkùnrin tó ni ilé ọ̀hún ló sọ iná sí ilé rẹ̀ fúnra rẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ná[.

Adekunle fi kun pé Salaudeen tó ni ilé náà ni òun àti ìyàwó rẹ̀ ti ń ní gbólóhùn asọ̀ láti bí ọdún méjì sẹ́yìn tó sì kó jáde kúrò nínú ilé tí wọ́n ń gbé.

Ilé àjókù

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE

Ilé àjókù

Oríṣun àwòrán, KWARA FIRE SERVICE

Salaudeen kó lọ sí ilé mìíràn tó kọ́ tò sí ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́.

Nígbà tó tún yá ni wàhálà tún bẹ́ sílẹ̀ láàárín Salaudeen àti ìyàwó rẹ̀ tó sì fi dandan le wí pé kí ìyàwó rẹ̀ náà kúrò nínú ilé náà ṣùgbọ́n tí ìyàwó kọ̀ láti kó jáde.

Ó ní èyí ló nínú tó sì ní tí ìyàwó àti àwọn ọmọ bá kọ̀ láti kó jáde òun máa dáná sun ilé náà.

Èyí ló fà á tó fi gbé epo bẹntiróòlù ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ló lọ sí ilé náà, tó sì da epo sí gbogbo ilé, tó sì ṣáná si.