Kíni ìdí tí ìjọba Nàìjíría kìí fí ṣé àmúṣẹ ìdájọ ikú fáwọn ọ̀daràn?

Aworan ọdaju niwaju adajọ

Labẹ ofin Naijiria idaju iku jẹ idajọ ti ile ẹjọ a maa gbe kalẹ lẹyin ti wọn ri pe ọdaran jẹbi ẹsun nla ti ko si ruju pe iru ẹni bẹ jẹbi.

Labẹ ofin awọn ẹsẹ taa n wi yi ninu wọn ni ẹsẹ iṣekupaniyan wa,eleyi to ni se pẹlu igbesunmọmi,idigunjale,ijinigbe,ibalopọ akọ sakọ,sisọ ọrọ bu ẹsin tabi Ọlọrun ati awọn ẹsẹ miran.

Bẹẹ naa lawọn ẹṣẹ kan labẹ fin ologun bi iditẹgbajọba ati ṣiṣe awọn ijọsin kan lawọn ipinlẹ ti wọn ti n lo ofin Sharia.

Labẹ ofin Naijiria, ifayesilẹ to wa fun idajọ iku ni ti iru ẹni naa ba jẹ oloyun.

Ni iru aaye bayi, wọn yoo yi idajọ iku yi si ẹwọn gbere.

Bakan naa ti wọn ba ri pe ẹni naa ko to ẹni ọdun mejidinlogun nigba to da ẹsẹ yi, wọn yoo yi idajọ iku yi pada si ẹwọn gbere.

Awọn ọna wo ni wọn fi n gbe idajọ iku kalẹ?

Ofin Naijiria la ọna ti wọnfi le gbe idajọ iku kalẹ.

Ninu wọn ni yiyẹgi fun ọdran,fifi ẹyin awọn ọdaran ti agba,lilẹko pa ọdaran,ati fifun daran labẹrẹ iku eleyi ti wọn fi kun lọdun 2015.

Kingdom Chikezie Collins to jẹ agbẹjọro ni ilu Port Harcourt ṣalaye pe awọn to niṣe pẹlu idajọ iku ni ile ẹjọ ti yoo sagbekalẹ bi wọn yoo se ṣe idajọ iku naa.

Lẹyin naa lo darukọ Gomina ti yoo buwọ lu aṣẹ pe ki wọn sọ idajọ yi di ododo.

Ẹni kẹẹta ni ẹni ti yoo ṣeku pa ọdaran naa.

Collins ni ofin ti ṣe tiẹ nipa alakalẹ idajọ iku, eyi to ku ni kawọn ti ofin gbe agbara fun lati se iṣẹ wọn.

”To ba jẹ ẹsẹ ti wọn da labẹ ijọba ipinlẹ, Gomina ni yoo buwọlu aṣẹ yi, to ba si jẹ eleyi ti wọn da tako ofin ijọba apapọ bi iditẹgbajọba, aarẹ orileede ni yoo buwọlu asẹ yi bi ti awọn Ogoni 9 ti aarẹ ologun Sani Abacha buwọlu nigba naa lọhun”

Ki lo de to fi ṣoro lati ṣe amuṣẹ idajọ iku gaan?

A ti sọ ṣaaju tẹlẹ pe ofin ṣe alakalẹ awọn ti yoo ṣe amuṣẹ idajọ iku.

Ni Naijiria loni ohun taa n ri ni pe ọpọ eeyan to yẹ ki wọn ti gbe idajọ yi kalẹ lori wọn ṣi wa ni ahamọ ọlọjọgbọọrọ.

Lọpọ igba gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro obinrin ni ipinlẹ Rivers Adata Bio-Briggs ṣe sọ, ọdọ awọn Gomiona to yẹ ko buwọlu aṣẹ iṣekupani yi ni ọrọ ti n wọ wa.

.”Ti ile ẹjọ giga ba gbe idajọ kalẹ,ọdaran lẹtọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun titi de ile ẹjọ giga julọ.Amọ bi wọn ba dajọ iku fun nibẹ, Gomina lo ku ti yoo buwọlu aṣẹ ki wọn ṣeku pa.Bi Gomina ba si kọ ti ko buwọlu lu,wọn yoo maa gbe ọdaran yi kaakiri lati ọgba ẹwọn ni ipinlẹ kan si omiran ni”

O ni ipenija nla leleyi jẹ nitori bi Gomina ko ba buwọlu aṣẹ yi, ko si ẹlomiran to le gba iṣẹ yi ṣe.

Bakan naa lo sọ pe ko si awọn oṣiṣẹ to n ṣeku pani mọ taa mọ si ”hangman”.

Wọn ko ri iṣẹ ṣe nitori pe ijọba naa ko buwọlu aṣẹ ki wọn pa eniyan tipẹ.

Awọn ti wọn ti gbe idajọ iku lelẹ fun latẹyinwa

Aworan Ken Saro Wiwa

Oríṣun àwòrán, TIM LAMBONI/GREENPEACE

Nigba ijọba ologun Naijiria ni wọn maa n saba gbe idajọ iku kalẹ ti wọn a si maa ṣe amuṣẹ rẹ.

Ninu awọn eleyi taa ranti ni idajọ iku fawọn ọdaran ni paapa to maa n waye lawọn bareke ologun tabi ni bar beach ni ipinlẹ Eko.

Wọn a tun maa ṣeku pa awọn to ditẹgbajọba ti ọwọ tẹ ni abẹ ijọb ologun.

Eleyi taa ranti to waye ti ijọba ologun ọgagun Sani Abacha gbe kalẹ ni ti ajafẹtọmọniyan ọmọ Niger Delta nii, Ken Saro Wiwa ati awọn mẹjọ miran ti ijọba sọ pe wọn gbimọran ọtẹ lati gbajọba.

Iku awọn wọn yi mu ki ọpọ ni Naijiria ati lagbaye bẹnu atẹ lu ijọba Naijiria .