Òkú obìnrin tí mò ń lọ wẹ̀ yọ sí mi, ohun tó sọ rèé – Agbókùújó

Itẹ oku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe bi airin jinna lai ri abuke ọkẹrẹ, ti eeyan ba de inu ibu, yoo ri ẹja to yarọ.

Ọkunrin agbookujo kan ti orukọ rẹ n jẹ Baffour Awuah ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nidi isẹ gbigbe oku to yan laayo.

Gbajugbaja agbooku lorilẹede Ghana ni Awuah jẹ, o si ti n ṣiṣẹ yii fun ọdun diẹ, ki oju rẹ to ri eemọ to ri yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awuah maa n wẹ fun oku, o si maa n wọ aṣọ fun wọn ṣaaju igba tawọn ẹbi wọn yoo lanfaani lati wa wo awọn oku naa fun igba ikẹyin.

Lọjọ kan ni ọkunrin yii n lọ si itẹ oku lati ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe e.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkọ ero ni Awuah wọ, ẹyin lo si joko si, ṣugbọn awọn ero mii naa joko si ẹyin pẹlu rẹ.

Ni kete ti o wọ ọkọ ọhun tan, ni obinrin kan to joko si ẹgbẹ rẹ pẹlu si ni ba a sọrọ.

Obinrin naa wa n beere lọwọ rẹ nipa ohun ibi ti o n lọ gan an ati ohun ti o n lọ ṣe nibẹ.

Agbooku yii ṣalaye fun obinrin naa pe oun n lọ wẹ fun oku obinrin kan ni, lẹyin naa ni oun tun maa wọ aṣọ fun oku ọhun.

Nigba naa ni obinrin sọ fun Awuah pe ki o wọ aṣọ fun oku naa daadaa lọna to boju mu.

Nigba ti awọn mejeeji de ibudokọ ti wọn ti sọ kalẹ, obinrin yii gba ọna tiẹ lọ, Awuah naa si mori le ọna itẹ oku to n lọ.

Iyalẹnu lo jẹ fun Awuah nigba to de ibi oloku to n lọ, ti o si fẹ wẹ fun oku ti wọn pe wa wẹ, amọ kayeefi lo jẹ fun pe oku to ba nilẹ jẹ ti obinrin ti wọn dijọ sọrọ ninu ọkọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa ni ko si iyatọ laarin oju obinrin ti o ba a sọrọ ninu ọkọ ati oku to fẹ wa wọ aṣọ fun.

Ti ọmọde ba de ibi ẹru, ẹru yoo ba a, ipaya ati ibẹru mu Awuah nigba to ri pe ero to ti n ba a sọrọ ninu ọkọ ni oku ti oun fẹ wọ aṣọ fun.

Idi si ree to se ni ki awọn ẹbi oku naa fun oun ni aworan oku naa to ya nigba to wa nile aye, ti jẹbẹtẹ si gbe ọmọ le Awuah lọwọ nigba to ri pe obinrin ti awọn dijọ wọ ọkọ papọ naa ni oku rẹ wa nilẹ.

Amọ, Awuah ṣe awọn eto kan lori oku naa, koda o da ọti Schnapps si oku naa lara ki o to wọ aṣọ fun un.

Awuah ni oriṣiriṣi iriri ni oun ti ri lẹnu iṣẹ agbooku, ṣugbọn ko le fi iṣẹ naa silẹ nitori awọn iriri yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ