“Taliban kò gbà kí obìnrin wọlé padà sílé ẹ̀kọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọjọ́ ọ̀la mi”

Ile ẹkọ ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn akẹkọọ ti wọle pada sile ẹkọ lẹyin ti ẹgbẹ Taliban gba ijọba lorilẹede naa.

Amọ, ijọba Taliban ko fun awọn akẹkọọbinrin lati wọle pẹlu awọn akẹgbẹ wọn ọkunrin.

Awọn akẹkọọ to jẹ ọkunrim atawọn olukọ ọkunrin nikan ni Taliban fun lanfani lati pada si yara ikawe wọn bayii.

Awọn akẹkọọbinrin to ba BBC sọrọ ṣalaye pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fawọn pe ijọba Taliban ko jẹ kawọn wọle pada sile ẹkọ.

Wọn ni okunkun birimu ni gbogbo nkan ṣe ri loju awọn bayii, ti ọpọ wọn si n beere pe ki ni yoo sẹlẹ si ọjọ ọla awọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹgbẹ Taliban to gbajọba loṣu to lọ ti sọ pe awọn n ṣiṣẹ lati gbe igbesẹ lori ọrọ naa.

Ọpọ lo n bẹru lẹyin ti Taliban pada sori aleefa pẹlu bi wọn ṣe fi ẹtọ awọn obinrin dun wọn lasiko ijọba wọn ni bi ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin.

Ohun ti Taliban sọ lẹyin ti wọn gba ijọba ni pe awọn obinrin yoo lanfani lati lọ ile ẹkọ, wọn yoo si maa ṣiṣẹ.

Ṣugbọn ohun ti ofin ẹsin Islam ba sọ nipa rẹ ni ijọba Taliban yoo tẹle.

Ni bayii, ijọba Taliban ti sọ pe kawọn obinrin to n ṣiṣẹ si fidi mọle na, titi ti eto abo to muna doko yoo fi wa.

Koda, awọn ẹṣọ Taliban ti fiya jẹ awọn obinrin to n fẹhonuhan lori bi ko ṣe si obinrin kankan ninu ijọba Taliban.

Lọjọ Ẹti, o dabi ẹni pe ẹgbẹ Taliban ti wọgile ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn obinrin, lẹyin ti wọn rọpo rẹ pẹlu ẹka to n ri si ọrọ ẹsin Islam.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ