Ohun tí a mọ̀ nípa ikú Olaolu Mudasiru, ọmọ gómìnà ìpínlẹ Eko tẹ́lẹ̀ tó di olóògbé rèé

Olaolu Mudasiru

Oríṣun àwòrán, VETIVA CAPITAL MANAGEMEN

Awọn ẹbi ati ọrẹ ti bẹrẹ si n ṣedaro Olaolu Mudasiru tojẹ igba keji adari ileeṣẹ Vetiva Capital Management (VCML) to di oloogbe niluu Eko.

Eyii n waye lẹyin ti iroyin iku rẹ jade lori ayelujara, to si da omi tutu sọkan awọn ololufẹ rẹ.

Ileeṣẹ VCML ti fidi iroyin iku oloogbe naa mulẹ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede loju opo Twitter rẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan jabọ pe afẹmọju ọjọ Aiku ni Laolu jade laye lẹyin ti awakọ kan fi mọto gba lasiko to n wa kẹkẹ lagbegbe Bourdilion, ni Ikoyi, niluu Eko.

Iroyin ni kete yi awakọ naa fi mọto rẹ gba Laolu tan lo fẹsẹ fẹ.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ko tii sọ nnkankan lori boya ọwọ awọn ti tẹ awakọ ọhun tabi bẹẹ kọ, amọ o fidi iroyin naa mulẹ.

Gbogbo igbiyanju BBC lati kan si Hundeyin lori ibi ti ọlọpaa ba iṣẹ de lo ja si pabo.

Pupọ ninu awọn ọrẹ ati mọlẹbi oloogbe naa lo ti bẹrẹ si n daro rẹ bayii loju opo Twitter wọn.

Ta ni Olaolu Mudasiru?

Ọjọ karun un, oṣu Kẹjọ, ọdun 1968 ni wọn bi oloogbe naa.

Oun ni akọbi ọmọ ọkunrin Gbolahan Mudasiru, to ti fi akoko igba kan ri jẹ gomina ologun ipinlẹ Eko.

Oun ni igbakeji adari ati oludasilẹ ileeṣẹ Vetiva Capital Management Limited.

O kẹkọọ gboye nipa imọ iṣegun ni fasiti UNILAG, to wa niluu Eko.

Laolu tun kẹkọọ gboye nipa owo ṣiṣe ni fasiti Reading, to wa nilẹ Gẹẹsi.

Ki lo ti Ṣẹlẹ sẹyin?

Ọmọ gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Eko kàgbákò ikú lójú pópó

Aworan

Oríṣun àwòrán, The nigerian Aristocrat/Twitter

Ọmọ gomina ologun nigba kan ri nipinlẹ Eko, Dokita Olaolu Mudashiru lo ti jade laye lẹyin ti ọkọ to n sa ere asapajude kan kọlu u nipinlẹ Eko.

Olaolu jẹ ọmọkunrin akọkọ gomina ologun nipinlẹ Eko, Gbolahan Mudashiru ti oun naa jade laye lọdun 2003.

Lowurọ ọjọ Aiku, nigba to n gun kẹkẹ rẹ lọwọ loju popo, ni ọkọ naa kọlu u, ti awọn eeyan meji miiran si farapa, ni agbegbe Ikoyi mipinlẹ Eko.

Lẹsẹkẹsẹ ni ọkọ ọhun sa lọ kuro nibi iṣẹlẹ naa.

Dokita Mudashiru ni igbakeji oludari ileeṣẹ Vitiva Capital.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin, fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni awọn meji miiran to farapa wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju, ti awọn si ti bẹrẹ iwadii.

O ni awọn ko tii mu ẹnikẹni lori isẹlẹ naa.