Àdúrà lásán ni mo gbà fún Peter Obi, mi ò ní agbára láti fa ọwọ́ rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ààre títún – Olubadan

aworan

Oríṣun àwòrán, PETER OBI/TWITTER

Agbẹnusọ fun Olubadan ti ilẹ Ibadan Oladele Ogunsola ni Ọba Sẹnetọ Lekan Balogun, Alli Okunmade keji ti ṣalaye awuyewuye lori fọnran ti o wa lori ayelujara nipa bi Kabiyesi Olubadan ti Ibadan ṣe n gbadura fun oludije ṣipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party gẹgẹ bii eke lati tan awọn ẹniyan jẹ.

A o ranti pe oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ Labour Party (LP) lo dari ikọ ipolongo rẹ lati ṣe abẹwo si Olubadan ni ọjọ Abameta to kọja yii ti awọn Oloye miran si darapọ mọ ọ lati gba alejo rẹ ni aafin Olubadan to wa ni Alarere nilu Ibadan.

Awọn Oloye ti o wa ni ijoko nigba ti Peter Obi wa ni, Otun Balogun ti Ibadan, Osi, Ashipa ati Ekerin Olubadan, Oloye agba Owolabi Olakulehin, Tajudeen Ajibola, Lateef Gbadamosi Adebimpe, Kola Adegbola, Eddy Oyewole ati Hamidu Ajibade.

Nigba ti Oloye Ajibola fesi si ọrọ ipolongo ti Peter Obi ba wa, ti Oloye Oyewole si gbadura fun un lori erongba rẹ.


Oladele Olusola ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ile BBC YORUBA ni adura nikan ni awọn oloye ṣe tí Olubadan funra rẹ kọ si sọrọ rara ninu fọnran ti wọn gbe sita.

O ni aṣa aafin ni lati gbadura fun gbogbo awọn ti wọn ba wa pe ki erongba wọn ko ṣẹ.

aworan

Oríṣun àwòrán, PETER OBI/TWITTER

O fi kun un pe Kabiyesi Olubadan ko fa ọwọ ẹni kankan soke nitori Peter Obi nikan kọ ni oludije ṣipo aarẹ ti yoo wa si aafin.

Olusola ni erongba awọn ololufẹ Peter Obi ni wọn gbe sori awọn ẹrọ ayelujara ti wọn si fi aafin olubadan ṣe ogbufo fun nitori ilẹkun aafin sii silẹ gbayawu fun gbogbo awọn oloṣelu ati gbogbo ara ilu.

Agbẹnusọ fun Olubadan ni ṣaaju ki ẹto ipolongo ṣipo aarẹ to bẹrẹ ni awọn oludije ti n wa ki Kabiyesi l’aafin, ninu eyi ti Rabiu Kwankwaso ati awọn oloṣelu miiran naa ti wa ki Olubadan.

Oni nnkan awada ni ki Olubadan gbe ọwọ ẹnikan soke ni gbangba nitori Ọba gbogbogbo ni Olubadan jẹ kii sii ṣẹ oloṣelu.