Ọ̀gá ọlọ́pàá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n lọ fi ṣìkún òfin mú àwọn ọlọ́kadà nílùú Eko

Kazeem Abonde

Oríṣun àwòrán, Kazeem Abonde

Ọga ọlọpaa kan, CSP Kazeem Sumonu Abonde, ti padanu ẹmi rẹ niluu Eko lasiko ti ija bẹ silẹ laarin awọn oṣiṣẹ igbimọ amuṣẹya to n gbẹsẹle ọkada.

Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ajao Estate lasiko ti awọn agbofinro lati ẹka RRS, igbimọ amuṣẹya to n gbẹsẹle ọkada atawọn ọlọpaa lati egbege naa lọ ṣawari awọn afurasi kan.

Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ẹmi ọga ọlọpaa ọhun sọnu lasiko ti wọn lọ fofin de awọn ọlọkada lagbegbe ọhun.

Ajisebutu sọ pe “Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn oṣiṣẹ wa yoo lọ mu awọn ọlọkada to kọti ikun si aṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lori ọkada wiwa lawọn agbegbe kan.”

“Awọn agbofinro n ṣiṣẹ naa lati mu adinku ba iwa ọdaran niluu Eko, a si ti fi sikun ofin mu ọpọlọpọ sawọn ọdaran nipasẹ irufẹ iṣẹ bẹẹ.”

“Ṣugbọn ọ ṣeni laanu pe lẹyin ti a fi ṣikun ofin mu awọn ọdaran kan tan ni Ajao Estate ni awọn ẹmẹwa wọn dena de awọn oṣiṣeẹ wa pẹlu ada, ibọn ati oniruru ohun ija oloro ti wọn si kọlu awọn eeyan naa nibi ti CSP Kazeem Sumonu Abonde ti jade laye.”

Ajisenutu tẹsiwaju pe yatọ si ọga ọlọpaa to ku yii, DPO agọ ọlọpaa to wa ni Ajao Estate, CSP Abdullahi Malla atawọn ọlọpaa mii tun farapa loriṣiriṣi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O fi kun pe awọn ti gbe oku ọga ọlọpaa to dagbere faye naa lọ sile igbokupamọsi.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun, o si ti paṣẹ ki iwadii kikun bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe irufẹ ikọlu bẹẹ ko ni waye mọ labẹ idari oun, ati pe iṣẹlẹ naa ko ni da omi tutu sọkan awọn agbofinro ipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ