Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí

NYSC ti sọja na

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Fidio kan to n ja ranyin lori ayelujara ti safihan bi ọmọogun obinrin kan, Chika Viola Anele, ṣe fi iya jẹ agunbanirọ obinrin ni ilu Calabar.

Agunbanirọ ti wọn fi iya jẹ naa, Ezeiruaku Ifenyinwa Fidelia, lo n sinru ilu ni ọ̀wọ́ Kẹtala ileeṣẹ ologun, 13th Brigade, to wa ni Calabar.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹsun ti sọja naa fi kan agunbanirọ ọhun ko han gbangba ninu fidio naa, amọ ariyanjiyan laarin wọn lo fa ijiya ọhun ba agunbanirọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu fidio naa ni a ti ri ọmọbinrin to wọ aṣọ agunbanirọ NYSC nibi to kunlẹ si, niwaju ọmọogun obinrin naa, to si bẹrẹ si da omi idọti to pọn le lori.

Bakan naa lo n fi abọ koto to fi n bu omi idọti naa lu ọmọbinrin agunbanirọ ọhun.

NYSC ti sọja na

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ki ni awọn ọmọ Naijiria n sọ lori iṣẹlẹ sọja to na agunbanirọ naa?

Ọpọlọpọ eniyan lo ti fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa, ti awọn kan ni bi o tilẹ jẹ pe agunbanirọ naa ṣẹ sọja ọhun, amọ o yẹ ko jẹ ki arabinrin naa bọ aṣọ agunbanirọ rẹ, ni ibọwọ fun aṣọ ilẹ wa naa.

Amọ awọn ẹlomiran ni awọn sọja kii dede fi iya jẹ araalu lai jẹ pe nkan kan ṣẹlẹ ni aarin wọn, to fa iru ifiyajẹni bẹẹ.

Ọkan lara awọn to fi ero wọn han ni, ibaṣepọ to dan mọran wa laarin awọn agunbanirọ ati awọn sọja, ti wọn si ma n bọwọ fun ara wọn.

”O ṣoro fun ọmọ Naijiria lati ri sọja to n na agunbanirọ nitori ibaṣepọ to wa laarin wọn, amọ nnkan to ṣẹlẹ yii gba suuru ati iwadii.”

”Nitori o ṣeeṣe ko jẹ pe ijiya to tọ si agunbanirọ naa ni abẹ ofin ologun, ni sọja naa fi jẹ obinrin naa.”

Nibayii, ileeṣẹ ologun Naijiria ti fesi si iṣẹlẹ naa, ti wọn si ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

A tọrọ aforiji lọwọ agunbanirọ naa, awọn ọrẹ rẹ nitori sọja naa ṣe ohun ti ko tọ – Ileeṣẹ Ologun

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nibi ti soja obinrin kan ti n fi iya jẹ agunbanirọ obinrin lori ikunlẹ.

Ileeṣẹ ologun ni iwuri ni ikọ ọmọogun Naijiria jẹ fun awọn ọmọ Naijiria amọ ohun itiju ati ifiyajẹ ọmọ eniyan ni iṣẹlẹ to waye naa.

”Ibudo ikọ ọmọogun 13 Brigade ni Calabar ni iṣẹlẹ naa ti waye, ti ijiya si ti bẹrẹ fun soja to hu iru iwa aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan naa.”

”Igbẹjọ soja naa ti bẹrẹ ni kiakia, a o si fi isi otitọ mulẹ fun awọn araalu lori iṣẹlẹ naa ati ohun ti iwadii wa gbe jade.”

”Nitori naa a tako ọrọ ti awọn araalu kan n sọ wi pe ileeṣẹ ologun fẹ fi ọwọ bọ iṣẹlẹ naa mọlẹ, eleyii ti ko dara to.”

” A n fi asiko yii da awọn araalu loju wi pe ako ni fi aye gba ki ọmọogun kankan fi iya jẹ araalu ni ọna aitọ nitori ibọwọ fun eto araalu jẹ wa logun.”

Ileeṣẹ ologun wa tọrọ aforiji lọwọ agunbanirọ ti wọn fi iya jẹ naa, awọn ẹbi rẹ, ọrẹ rẹ, Ajọ Agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC ati gbogbo awọn ọmọ Naijiria ni apapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni ajọ NYSC se lori agunbanirọ ti sọja lu?

Nibayii, iroyin kan ti ko fidi mulẹ ni Ajọ NYSC ti n sa gbogbo agbara rẹ, lati ri pe agunbanirọ naa ko duro si ilu Calabar mọ, lẹyin ti ileeṣẹ ologun fi panpẹ mu sọja to na a.

Iroyin ọhun ni wọn ti fun ni owo irinna lati kuro ninu ilu fun eto aabo rẹ.

Amọ ileeṣẹ iroyin lori ayelujara ”Cross River Watch” ti kede pe, agunbanirọ naa ni awọn alaṣẹ ajọ NYSC ti wọn jẹ sọja naa ko jẹ ki ọmọbinrin naa kuro ni Calabar.”

”Ti wọn si fẹ ki o pada si ilu Eko,lẹyin ti wọn tun gba ẹrọ ibanisọrọ foonu rẹ.”

Ọpọlọpọ igba ni awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti ma n fi ẹsun kan ileeṣẹ ọmọogun Naijiria pe wọn ma n fi iya jẹ araalu lọna aitọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ