Óṣe! Onífàyàwọ́ epo bẹntiróòlù kan àti ìyàwó rẹ̀ jóná mọ́lé , wọ́n fi ọmọ osù mẹ́rin sílẹ̀ sáyé

Àwọn ènìyàn tó tò láti ra epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, Others

Ìṣẹ̀lẹ̀ láabi kan bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú Jos, olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau bí ọkùnrin kan tó jẹ́ olówò epo bẹntiróòlù, Gideon Pam àti ìyàwó rẹ̀ jóná malé nínú ìjàmbá iná tó sọlè ní ilé ìgbé wọn.

Òkú Pam àti ìyàwó rẹ̀, Mercy ló jóná ráúráú níbi ìjàmbá iná tó bẹ̀rẹ̀ láti ilé ìdáná wọn tó sì gba gbogbo ilé kan.

Ìròyìn ní èpò bẹntiróòlù tí Pam gbé sílé fún títà gẹ́gẹ́ bí oníbàràǹdà bí ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù ṣe ń bá ìlú fínra ló ṣe okùnfà iná náà.

Báwo ni ìjàmbá iná náà ṣe wáyé?

Ìròyìn ní àwọn onílé epo kan ló pe Pam láti wá gbe epo bẹntiróòlù ti wọ́n ti bá a tà kalẹ̀, èyí ló mú Pam sáré lọ sí ilé rẹ̀ láti lọ gbé gálọ̀nù tí yóò ra epo náà sí.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nígbà tó délé, tó ń gbìyànjú láti da bẹntiróòlù kúrò nínú àwọn gálọ̀nù tó ní epo bẹntiróòlù láti lọ fi ra èyí tí wọ́n pè é sí nínú ilé ìdáná wọn ni iná náà ṣẹ́yọ.

Iná yìí gbilẹ̀ tó sì gba gbogbo ilé kan débi pé Pam kò ríbi móríbọ́ nínú ìjàmbá náà.

Bawo ni Tokotaya se wa jọ jona mọ́le?

Ìyàwó Pam fẹ́ dóòlà ọkọ rẹ̀ ni òun náà fi há sínú ìjàmbá iná náà.

Bí iná yìí ṣe ń jó ní Mercy darí sílé láti ọjà ló ba tí èéfí ń ṣẹ́yọ láti ilé wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ní kété tó gbọ́ wí péw ọkọ òun ti ha sínú iná náà ní òun náà bá sáré wọlé láti lọ dóòlà ọkọ rẹ̀ nínú ìjàmbá iná yìí ṣùgbọ́n tó jẹ́ òkú òun náà ni wọ́n gbé jáde níbẹ̀.

Alábàgbé àwọn tọkọtaya náà, Shantel Alphonsus ṣàlàyé pé oníbàràǹdà epo bẹntiróòlù ni Pam ní oríta Zawan ní Jos.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alphonsun fi kun pe ọmọ oṣù mẹ́rin ni àwọn tọkọtaya náà fi si ayé lọ.

Ó ní ìyá Pam ló gbé ọmọ náà ṣeré lọ ní òwúrọ̀ kí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà tó wáyé.

Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Plateau, Caleb Polit fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ àti pé gbogbo ilé náà ti jó tán kí àwọn tó le dé ibẹ̀.