Adájọ́ ní kí wọ́n fi Tọkọtayà tí wọ́n ka ẹ̀yà ara mọ́ lọ́wọ́ sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n ní Obafemi Owode

Ile awon afurasi naa

Saaju leyin ti ọwọ́ agbofinro ti tẹ́ awọn Tokotaya yii ni ọ̀rọ̀ naa ti se ọ̀pọ̀ ni kayeefi.

Onidajọ I. O. Abudu paṣẹ pe ki Kẹhinde Ọladimeji to jẹ́ ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Adejumọkẹ Raji ti oun naa jẹ́ ẹni ọdun marundinlọgbọn lọ maa gbadun ara wọn ni atimọ́le to wa ni Obafemi Owode nipinle Ogun titi igbẹjọ miran yoo fi waye.

Tokotaya Leme

Kini o sele nile ẹjọ́ bayii?

Adajọ ile-ẹjọ giga t’ipinlẹ Ogun to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta ti paṣẹ pe ki wọn fi ọkọ at’iyawo naa si ahamo.

Awon Tokotaya naa ni wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ lagbegbe Lẹmẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun pamọ si ọgba ẹwọn to wa ni Ọba, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki loun to ṣẹlẹ gan-an?

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii ni aṣiri Kẹhinde ati Adejumọkẹ tu sita pẹlu ẹya ara oku ni ojule kejilelaadọrin, opopona MKO Abiọla, Lẹmẹ.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe awọ ara agbegbe Lẹmẹ yii ṣakiyesi ageku oku kan leti odo, ti wọn ko si mọ bo ṣe debẹ, eyi lo jẹ ki wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa agbegbe Kemta, Idi Aba, ti wọn si bẹrẹ iwadii lori ẹ.

Lẹyin ọsẹ meji la gbọ pe aṣiri awọn ọkọ at’iyawo yii tu pẹlu ẹya ara oku ti wọn gbe pamọ sinu ike omi nla ninu yara wọn. Lẹyin o rẹyin la gbọ pe Ifẹoluwa Adeh, ọmọ ọdun mejilelogun ni wọn tan lati pa danu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adajo Abudu sọ̀rọ̀ ilẹ́ kun lori idi ti ileejọ́ ko fi ni gba beeli wọ́n:

Adajọ ile-ẹjọ naa, Onidajọ I. O Abudu kọ lati gba ẹbẹ awọn t’ọkọ-t’iyawo naa.

O salaye idi ti ile ejo ko se ni fi oju aanu wo wọn.

Eyi lo fi so pe ki wọn lọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn to wa ni Obafemi Owode ni ipinle Ogun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

.Kini awọn agbejọ́rò sọ?

Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro fawọn ọlọpaa, Oluwatosin Jacson ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii lawọn mejeeji ṣe ẹṣẹ naa.

O ni ṣe ni awọn mejeeji pawọpọ lati tan Ifẹoluwa Adeh, ẹni to jẹ ọrẹ timọtimọ si Adejumọkẹ wa sile wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbehoro naa ni pe nigba ti wọn tan Ifẹoluwa de ile wọn, wọn dana fun, wọn si fi oogun orun sinu ounjẹ naa, lẹyin eyi ni wọn dumbu ẹ, ti wọn si ta ori rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọrin naira fun babalawo kan niluu Ibadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Esun wo ni wọ́n fi kan Tokotaya naa bayii nile ẹjọ́?

Ẹsun ti wọn ka si awọn mejeeji yii lẹsẹ la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran t’ipinlẹ Ogun, t’ọdun 2006, aba;a 324 ati 319(1).

Onidajọ Abudu wa sun igbẹjọ miran si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii.