Ọkùnrin tó lo ọdún 48 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa rẹ̀ gba òmìnira

Glynn Simmons

Oríṣun àwòrán, NEWS9, OKLAHOMA CITY KWTV

Adajọ kan nipinlẹ Oklahoma, nilẹ Amẹrika, ti tu ọkunrinn ẹni aadọrin kan silẹ lọgba ẹwọn lẹyin to ti lo nnkan bii aadọta ọdun ni ahamọ lori ẹsun ipaniyan to waye lọdun 1974.

Glynn Simmons gba ominira lẹyin ti adajọ ni ki wọn tun ẹjọ rẹ ṣe bo tilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro ijọba ni ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ pe ki wọn ṣe ẹjọ miran.

Amọ lẹyin gbogbo ayẹwo ati atotonu, adajọ Amy Palumbo sọ pe ọgbẹni Simmons ko mọwọ-mẹsẹ ninu ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ ọhun ni “Ile ẹjọ yii ri pẹlu aridaju pe kii ṣe ọgbẹni Simmons lo wu iwa ọdaran ti wọn fi pe e lẹjọ ati eyii to ṣẹwọn fun.”

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Associated Press sọrọ, Simmons sọ pe o jẹ ẹkọ nla fun oun lati maṣe sọ ireti nu.

O ni “Maṣe jẹ ki ẹnikẹni sọ fun ọ pe ko le ṣeeṣe, nitori ko si ohun ti ko ṣeeṣe.

Simmons lo ọdun mejidinlaadọta, oṣu kan ati ọjọ mejidinlogun lọgba ẹwọn ko to gba itusilẹ.

Ọkunrin naa kagbako ọgba ẹwọn lẹyin idigunjale kan to waye nile itaja ọtin kan nipinlẹ Oklahoma, nibi ti ẹnikan kan, Carolyn Sue Rogers, ti jade laye.

Gẹgẹ bii akọsilẹ ajọ National Registry of Exonerations, Simmons ni ẹni to pẹ julọ lọgba ẹwọn to gba itusilẹ lẹyin ti adajọ ni ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ẹni ọdun mejilelogun pere ni Simmons nigba ti oun ati ekeji rẹ ti wọn fẹsun kan, Don Roberts, gba idajọ iku lọdun 1975.

Ko pe lẹyin naa ti wọn yi idajọ naa pada si ẹwọn gbere, iyẹn lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ l’Amẹrika pa ohun da lori idajọ iku nilẹ naa.

Simmons ni ilu oun lagbegbe Louisiana loun wa lasiko ti iṣẹlẹ ipaniyan ọhun waye lọdun naa lọhun.

Awọn to ba ṣẹwọn lori ẹsun ti wọn ko mọ nnkankan nipa rẹ lẹtọọ si owo gba mabinu ti iye rẹ to $175,000 nipinlẹ Oklahoma.