Iléẹṣẹ́ Ọlọ́pàá gbẹ̀wù lọ́rùn àwọn ọlọ́pàá tó béèrè owó lọ́wọ́ arìnrìn-àjò l’Ọ̀yọ́

Aworan bi wọn se gba ẹwu lọrun awọn ọlọpaa mejeeji

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Oyo tí fi ọwọ osi juwe ile fun awọn Ọlọpaa meji kan ti wọn n bere owo lọwọ arin irinajo kan nipinlẹ Oyo.

Kọmisọna fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Hamzat Adebola lo kede igbesẹ yii Lọjọbọ, Ọjọ kọkanlelogun oṣu Kejila ọdun 2023 ni ọfisi wọn ní Eleyele Ibadan.

Awọn Ọlọpaa mejeeji ti orukọ wọn n jẹ Jimoh Lukmon ati Kareem Fatai ni wọn wa lẹnu isẹ ni oju ọna opopona Moniya si Iseyin nigba ti fọnran kan lati ọwọ arin irinajo bọ sori ayelujara to si safihan wọn nibi ti wọn ti n bere owo lọwọ rẹ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, saaju ni fọnran kan jade, eyi to safihan bi awọn ọlọpaa meji se da arin irinajo naa duro, ti wọn si n bere pe nibo lo n lọ.

Fọnran to le ni isẹju kan yii lo fa rogbodiyan lori ayelujara, ti ọpọ si bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹlu iwa awọn ọlọpaa naa.

Ninu fọnran naa, ọlọpaa da obinrin arin irinajo lori ọkada naa duro, to si bere pe nibo lo ti n bọ ati pe ibo lo n lọ.

Obinrin naa da lohun pe lati orilẹede Netherlands ni oun ti wa, ti oun si n lọ Abuja , eyi to ya awọn ọlọpaa meji naa lẹnu.

Ọlọpaa naa kọnu si obinrin arin irinajo naa pe “ki lo ba oun mu bọ? Ki lo fo fẹ fun mi? O ya wa nnkan fun mi,”

Arin irinajo ni ọrọ naa ko kọkọ ye arin irinajo, ti ọlọpaa naa si ni lati mọlẹ fun pe ko fun lowo, ti obinrin naa si bere pe fun kinni.

Kọmnisana ni gbigbe ẹwu awọn ọlọpaa naa ko sẹyin iwadii ajọ to n se iwadii iwa awọn ọlọpaa.

O ni Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ko ni fẹ iwuwasi awọn ọlọpaa naa, to si ni oun ko ni fi aye silẹ fun iru iwa itiju naa.

Adebola wa se ikilọ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa yoo fiya jẹ ẹnikẹni ti iru iwa naa ba wa lati ọwọ rẹ.

“A ko ni gbe awọnb ọlọpaa mejeeji ti a gba ẹwu lọrun lọ si ileẹjọ nitori wọn ko kọ ẹkọ lati ileeṣẹ ọlọpaa.