NÍ YÀJÓYÀJÓ Àwọn Agbébọn ṣe ìkọlù sí àgọ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Imo, wọ́n pa Ìsìpẹ́kítọ̀

Copyright: Getty Images

Awọn abanikẹdun n yi posi oku naa ti wọn fi gbe Biṣọọbu agba, Desmond Tutu gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe isin idagbere fun un ni ijọ St. George’s Cathedral to wa ni Cape Town, South Africa.

Tutu, to jẹ ẹni to ti gba ami ẹyẹ iyebiye eyi to ṣeranwọ to si wulo gan fun awọn ẹya ti wọn di apati lorilẹede South Africa dagbere faye lẹni ọdun aadọrun.

Awọn oloṣelu ati adari oniruuru ẹsin korajọ si Cape Town lati bu iyi ikẹyin fun Biṣọọbu agba Desmond Tutu.

Ayẹyẹ ikẹyin ti gbogbo awọn eeyan oniruuru ẹsin korajọ ṣe fun akinkanju ajafẹtọ awọn ti wọn pa ti ni iroyin rẹ gba gbogbo igboro kan.

Ọpọlọpọ eeyan lo lo anfani eto naa lati fọnrere oloogbe Desmond Tutu.

Ẹwẹ, eto isinku ti orilẹede gangan yoo ṣe fun un yoo waye ni ọjọ Abamẹta ọjọ Lini, oṣu kini ninu ọdun 2022.

Bakan naa lẹyin eto isinku ọjọ Satide, wọn yoo dana sun okú tutu ni ilana to yẹ ki wọn tẹle.

Bẹẹ si ni eeru ti wọn ba ko jọ ni wọn yoo gbe pamọ sinu ijọ Cathedral nibi to ti waasu fun ọpọlọpọ ọdun.

Bakan naa, awọn araalu yoo lanfani lati sọ ọrọ idagbere wọn fun ẹni ọwọ pupọ yii laarin ijọ to tun jẹ irinṣẹ pataki fun mimu opin de ba aṣa pipa ẹya kan ti lorilẹede.

Eyi jẹ ilana kan ti ijba awọn oyinbo alawọfunfun gbe kal ni dandan lodi si awọn eeyan alawọdudu to wa ni orilẹede South Africa laarin ọdun 1048 si ọdun 1991.

Copyright: Getty Images

Copyright: Getty Images