Fídíò, Èmi ni mo nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́- Ìyá Emmanuel tó kú ní ilé ẹ̀kọ́ CAC, Duration 7,56

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

JSS 3 boy hits his head in CAC school Akure: Dókìtà tó yẹ̀ ẹ́ wò ní ó pẹ́ tó ti kú, àlàyé la bèrè, kí ló dé tí wọ́n gbé owó jáde pé ká gbà?

“Kí ló dé tí wọ́n sáré ń gbé owó gbà má bínú wa fún wa nínú ọ̀fọ̀ ọmọ”?

Mọlẹbi Emmanuel Ojo tí iroyin tan kan ni bii ọjọ diẹ sẹyin pe o fori gbalẹ latoju ferese to ti fo jade ni ilu Akure sọ pe o da bii pe awọn iṣẹlẹ kan wa to yi iku ọmọ awọn ka amọ ti awọn to wa nibẹ ko jẹ ki otitọ rẹ han jade.

“Gbogbo ohun ti wọn n sọ pe o n pọ ẹjẹ lẹnu, ni imu ati eti, awa o ba bẹẹ o, oku ni mo baa, koda emi ni mo bọ gbogbo aṣọ rẹ”. Iya Emmanuel sọ fun BBC Yoruba.

Ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ ni iroyin naa gba igboro kan pe Emmanuel Ojo fẹ fo jade lati oju ferese kilaasi rẹ ni lo ba fori gbalẹ. Amọ ẹbi ni awọn ọrọ yii ṣokunkun tori ko jọ ara wọn loju awọn.

Pasitọ Ojo Joshua to jẹ baba Ojo Emmanuel ni ko si aisan kankan to ṣe ọmọ ohun tori o ni awọn nkan to maa n ṣe laraarọ to si ṣe bẹ lọjọ naa ko to lọ ileewe.

“O ji laarọ, a gbadura fun un, o pọn omi sile, o dana, o jẹun, mo fun un lowo amudani, o si lọ si ile ẹkọ”.

Pasitọ Joshua ni ojoojumọ loun maa n fun un lowo ti wọn ba ti bẹrẹ ile ẹkọ to si ni o de ile ẹkọ lalafia.

Iya rẹ , Wolii Omolade Ojo ni Emmanuel o ba ẹnikẹni ja ri latigba ti oun ti bii ko si si olukọ to wa fi ẹjọ rẹ sun ri.

“Wọn pe mi ni nkan bii ago meji ọsan pe ọmọ mi ṣaisan, mo si ni aisan kẹ, mo lọ sibẹ”.

Baba rẹ ni kia loun gbe ọkada lọ pẹlu eeyan kan lọ si ile iwosan ti wọn juwe fun awọn.

“Mo de ibẹ, wọn ni wọn o gbe ọmọ ile ẹkọ kankan wa, mo tun pe olukọ rẹ o ni ki n duro si ẹnu geeti, mo duro titi titi, ki wọn to gbe e de ninu ọkọ taxi, mo ba wo o ninu ọkọ naa”.

O ṣalaye pe awọn dokita to ṣe ayẹwo rẹ sọ pe o pẹ to ti ku.

Lati bii ago mẹsan ti ẹni to wa ni ile iwosan ti ile kọ wọn ti ni wọn gbe e wa sọdọ oun, nkan bii ago meji ni baba rẹ to gba ipe.

Dokita to jẹ onimọ iṣegun oyinbo fun ẹbi Ojo, Ilesanmi Michael ni pẹlu nkan to ṣe ọmọ yii ti wọn ṣalaye, ko ṣeeṣe ki wọn fun ọmọ ni abẹrẹ eyi ti wọn juwe bi eyi ti wọn maa n fun ẹni to ba daku lati taji.

Bakan naa lo ni ọrọ ni awan fẹ mọ bi iku naa ṣe ṣẹlẹ ti awọn si lọ beere, afi ti wọn gbe owo jade ti wọn ni ile ẹkọ naa sọ wipe ki wọn gbe owo fun wọn – “owo kini?”

“Kí ló dé tí wọ́n sáré ń gbé owó gbà má bínú wa fún wa nínú ọ̀fọ̀ ọmọ?”

Iya rẹ ni gbogbo iroyin ti wọn n gbe kaakiri nipa bi ọmọ oun ṣe ku jẹ ohun to ba oun ninu jẹ ju… “mo fi ọrọ yii le kootu Ọlọrun pe Ọlọrun ni ko ba mi da a”.