Mi ò retí kí àwọn ọmọ Naijria gbóríyìn fún mi lẹ́yìn ìṣèjọba mi – Buhari

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad

Aarẹ orilẹ-ede Naijriia, Muhammadu Buhari sọ pe oun ko reti ki awọn ọmọ Naijiria yin oun lẹyin to ba pari saa iṣejọba rẹ.

Iwe iroyin Cable jabọ pe aarẹ sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwanilẹnuwo to sẹ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan NTA ni Ọjọbọ.

Buhari sọ pe gbogbo nkan to wa ni ikapa oun ni oun ṣe fun orilẹ-ede Naijiria lasiko ti oun fi jẹ aarẹ.

O ni ireti oun ni pe nigba ti iṣejọba oun ba pari ni ọdun 2023, awọn ọmọ orilẹ-ede yoo ri i pe oun ṣe nkan ti agbara oun ka.

Aarẹ ni “oriṣiriṣi ọna ni mo ti gba sin orilẹ-ede yii. Mo ti sẹ gomina, minisita, mo si tun ti ṣe aarẹ fun igba meji.

Ki lo tun ku ti mo fẹ ẹ ṣe fun orilẹ-ede yii ti mi o ti i sẹ?

“Mo sẹ iwọn ti mo le ṣe. Nkan ẹyọkan ti mo n reti nigba ti mo ba kuro ni ipo aarẹ ni pe ki awọn ọmọ Naijiria sọ̀ pe ọkunrin yii ṣe iwọn to le ṣe fun Naijiria,” Buhari lo sọ bẹẹ.

Aarẹ Naijiria tun sọ pe ijọba oun ko le da olori ẹgbẹ ajijagbara nilẹ Igbo silẹ,IPOB, Nnamdi kanu silẹ.

Buhari ṣalaye pe Kanu gbọdọ ṣalaye ara rẹ nile ẹjọ pe oun o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.

Buhari ni ”awọn ọmọ Naijiria ko mọ pe n kii dasi ọrọ ile ẹjọ.

Fun gbogbo awọn ti wọn n sọ pe ki a fi Kanu silẹ, a ko le fi i silẹ bayẹn.

A ṣi le lo oṣeleu lati yanju ọrọ naa tawọn ti ọrọ kan ba huwa daadaa ṣugbọn ẹnikan ko le lọ joko si oke okun ki o si maa da Naijiria ru lati ibẹ.”