Àwa náà ṣetán láti ma gbé oúnjẹ àti máàlù wà silẹ Igbo- Oloúnjẹ̀ ilẹ̀ Àríwá

Darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbarijọpọ awọn oniṣowo ounjẹ jíjẹ ati awọn onimaalu ti sọ pe awọn ṣetan lati dawọ tita ounjẹ ati ẹran fawọn eeyan agbegbe ilẹ Igbo ni Naijiria.

Ọrọ wọn yi jẹ gẹgẹ bí esi satẹjade ìkọ ajijagbara Biafra IPOB to sọ kọkọ Aje pe awọn ti wọgile gbigbe ounjẹ tabi maalu wa lati ile Ariwa wa si ọdọ awọn bẹrẹ lati oṣu kẹrin ọdun yi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, alaga awọn ẹgbẹ olounjẹ, Muhammad Tahir ni rẹgi ni ọrọ ti IPOB sọ ṣe lara awọn.

IPOB ṣẹṣẹ kéde ni ọjọ ọdun tuntun pe ko ni si kikọ orin orileede Nàìjíría l’awọn ile ẹkọ lagbegbe naa ati pe awọn kò ní faaye gba ki wọn máa jẹ ẹran maalu lagbegbe ohun.Tahir sọ pe “a fẹ kí Naijiria ṣọkan ṣugbọn o ti wa hàn kedere bayi pe wọn o fe bẹẹ”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tahir tẹsiwaju pe oja táa n gbe fún wọn,ounjẹ ni,kìí ṣe majele ti yoo sakoba fún wọn”.

“Tori naa ẹni ta bàa n gbe ounjẹ wa fuun to sì sọ pe oun ko fẹ, Se o wa fẹ fi ẹmi rẹ sinu ewu lati gbe lo fún ni?”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alaga ẹgbẹ yi sọ pé ibanilorukọ jẹ ni awon ara ilẹ Igbo n ṣe ati pe ọrọ naa ti su awọn bayii.O ni awọn ara ilẹ Igbo ko le da ọjọ kan ṣe lalae ri ẹran tàbí ounjẹ tàwọn n gbe wà fún wọ́n.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lọjọ Aje ni IPOB kéde pe ki wọn ma se kọ orin orileede Naijiria ki wọn sì má jẹ ẹran maalu to bá n bi wa lati ilẹ Ariwa Naijiria.Eleyi jẹ ọkan lára àwọn ofin meje ti wọn lawon yoo bẹrẹ sí ní fidi rẹ múlẹ lọdun 2022.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn nkan mii ti wọn l’awọn yóò máa ṣe ni pé àwọn yóò bẹrẹ ipolongo fawọn ọmọ ẹgbẹ àwọn tó wà àhámọ́.Wọn ní awọn wọn yi ko dẹṣẹ kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bẹẹ won ni awọn yóò ṣe ipolongo kakiri agbaye láwọn ilu nla.Agbegbe guusu ila oorun Naijiria ti n koju ipenija ọwọngogo ounjẹ nigbakigba tàwọn olounjẹ lati òkè ọya ba da’se silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ