Ìyá arúgbó dìde nínú pósí bí wọn ṣe n múra làti sìn òkú rẹ̀

Aworan awọn to gbe posi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ara meeriri kan lo tun waye ni orilẹede Ecuador eyi to gbẹnutan.

Iya arugbo kan, Bella Montoya, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lo ku, ti gbogbo ẹbi si ti ṣaaju kede lọsẹ to kọja pe o dagbere fun duniyan.

Isinku lawọn ẹbi ati ara lero pe awọn wa ṣe fun iya agba naa lai mọ pe sise si ku fun.

Iyalẹnu nla si lo jẹ fun wọn nigba ti wọn ṣadede ri wi pe ẹni tawọn wa sinku rẹ ṣi wa laaye, ninu posi ti wọn gbe si.

Nkan bi wakati marun un si igba ti wọn yoo ṣe isin ikẹyin fun oku iya agba naa lọjọ Ẹti, ni awọn mọlẹbi bẹrẹ si ni paarọ aṣọ fun iya ninu posi ti wọn gbe si..

Ẹnu si ya wọn bi wọn ṣe ri ti iya naa bẹrẹ si ni mi soke silẹ.

Wọn ti gbe arabirin Montoya pada lọ si ileewosan, ti ẹka ileeṣẹ ilera.

“Ni bayii mo kan n gbadura ni pe ki ara iya mi ya, mo fẹ ko wa laaye, ko si wa pẹlu mii.”

Ninu fidio kan ti wọn ṣe alabapin rẹ loju opo ayelujara, o ṣafihan bi iya naa ṣe n mi soke silẹ, tawọn eeyan si rọ yi posi rẹ ka.

A ri ti awọn oṣiṣẹ ilera sare de pẹlu ọkọ ambulaansi, ti wọn si ṣe ayẹwo arabinrin Montiya, ki wọn to gbe si inu ọkọ naa lọ si ile iwosan.

Ni bayi, wọn n ṣe itọju lọwọ fun iya naa ni ile iwosan ti wọn ti ṣaaju sọ pe o ti ku.

Ileeṣẹ iroyin AFP sọ pe arakunrin Balberán ni : “Diẹ diẹ ni nnkan to ṣẹlẹ ṣẹṣẹ n ye mi.

Ni bayii mo kan n gbadura ni pe ki ara iya mi ya, mo fẹ ko wa laaye, ko si wa pẹlu mii.”

Orilẹede Ecuador si ti gbe igbimọ kalẹ lati ṣe iwadii nipa nnkan to mu isẹlẹ kayeefi naa waye.

Lẹyin o rẹyin, iya agba naa jade laye

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ilera orilẹede Ecuador fisita, o sọ pe iya agba yi ni ipenija lati mi kanlẹ, ti ọkan rẹ naa ko si gbe iṣẹ mọ.

Wọn ni gbogbo igbiyanju lati jẹ ki ẹmi rẹ sọ pada, lo ja si pabo.

Dokita to wa lẹnu iṣẹ lasiko ti iṣẹlẹ yii waye jẹri si pe iya naa ti rebi agba ree.

Ọmọ iya taa n wi yii, Gilber Rodolfo Balberán Montoya, lawọn iwe iroyin labẹle sọ pe o ni-

”nkan bi ago mẹsan owurọ ni iya mi de ile iwosan, nigba ti yoo fi to aago mejila ọsan, awọn dokita sọ pe wọn ti ku”

O ni awọn gbe iya si inu posi fun ọpọ wakati titi di igba tawọn mọlẹbi ri, ti iya n gbiyanju lati mi.