Godswill Akpabio di ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, ó fẹ̀yìn Abdulaziz Yari janlẹ

Godwin Akpabio

Oríṣun àwòrán, Godwin Akpabio

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti fihan pe Sẹnatọ Godwin Akpabio ti jawe olubori gẹgẹ bii aarẹ ile asofin agba nilẹ wa.

Akpabio lo fi ẹyin alatako rẹ, Abdulaziz Yari janlẹ ninu eto idibo naa to waye laarọ oni nile asofin apapọ ilẹ wa nilu Abuja.

Ibo mẹtalelọgọta ni Akpabio ni , to se fi ẹyin Yari janlẹ, ẹni to ni ibo mẹrindinlaadọta.

Apapọ ibo ti wọn di si jẹ mọkandinlaadọfa.

Ọpọ awọn oloselu ati lookọ lookọ lo waye peju sile asofin apapọ naa, to fi mọ awọn gomina atawọn oloselu kanka.

Se ni ọpọ awọn asofin fo fun ayọ nigba ti wọn kede pe Akpabio lo moke ninu eto idibo naa.

Bẹẹ ba gbagbe, awuyewuye ti gbalẹ kan lati bii ọjọ melo sẹyin lori ẹni ti yoo di aarẹ ile asofin agba ati olori ile asoju sofin.

Nibayi na, wọn ti n se ibura fun Senatọ Godwin Akpabio gẹgẹ bii aarẹ ile asofin agba kẹwa.

Ile asofin apapọ

Ki lo ti waye saaju?

Awuyewuye lori ta ni yoo di aarẹ ile asofin agba lo n waye lẹyin ti awọn aṣofin saa kẹsan an ṣe isin idagbere ni Ọjọ Satide.

Ki o to di oni, aarẹ Bola Tinubu ni iroyin gbe pe o ṣe atilẹyin fun ṣẹnetọ Godswill Akpabio lati di aarẹ ile igbimọ Aṣofin agba.

Bakan naa ni wọn ni aarẹ buwọlu Tajudden Abbas ati Ben Kalu lati di abẹnugan Ile Igbimọ aṣojusọfin ati igbakeji rẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Twitter

Awọn wo lo dije du ipo?

Bi o tilẹ jẹ pe aarẹ Tinubu ati awọn aṣofin miran ṣe atilẹyin fun Godswill Akpabio ati Barau Jibrin, ati Tajudeen Abbas ati Ben Kalu fun Ile Igbimọ asọjuṣofin, o ṣeese ki ọrọ bẹyin lọ.

Amọ nigba miran kii ṣe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC lo buwọlu ẹni ti ẹgbẹ yan laayo.

Gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, Sẹnetọ Abdulaziz Yari naa n fi ero rẹ han lati sije du ipo adari naa ti Idris Wase si n dije fun ipo igbakeji.

Bakan naa ni Sani Jaji ni oun naa yoo dije du ipo.

Ẹni to di ipo Chief Whip mu, Orji Uzor Kalu lati ipinlẹ Abia ti gba lati jawọ ninu idije naa.

Awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan jẹ 109, nigba ti awọn ṣẹnetọ ti wọn dibo yan jẹ 360, ti wọn yoo si maa burawọle fun wọn loni lati bẹrẹ iṣẹ.