Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo sọ ohun tó pa Akeredolu àti ibi tí ó kú sí

Lucky Aiyedatiwa ati Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Arakunrin Akeredolu/X

Lati aarọ Ọjọru ti iroyin iku gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti gba ori ayelujara kan lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii nipa ohun to ṣeku pa a ati ibi ti o ku si gan an.

Ọpọ ileeṣẹ iroyin atawọn eeyan kan lo ti n sọ pe ilu Eko ni o ku si, koda awọn kan tun sọ pe niṣe wọn n wa ẹrọ ”dialysis” ti wọn maa fi n ṣe itọju awọn to ba ni arun jẹjẹrẹ kaakiri ilu Eko ki ẹlẹmii too gba a.

Amọ, ijọba ipinlẹ Ondo ti tan imọlẹ si ọrọ naa pẹlu atẹjade ti wọn fi sita lori iku Akeredolu.

Ninu atẹjade ti Bamidele Ademola-Olateju, Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Ondo, fi sita, o ni gomina Akeredolu fọwọ́ rọri ku ni owurọ kutukutu Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

“Gomina Akeredolu jẹ ipe ayeraye nibi to ti n gba itọju ni orile-ede Germany.

“O ku nitori aisan jẹjẹrẹ to mu ni koropọn.”

Ọgbẹni Ademola-Olateju sọ pe awọn ti kọ lẹta ranṣẹ si Aarẹ Bola Tinubu, lati fi iroyin iku gomina to o leti.

O ni awọn yoo kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ.

Bakan naa ni o ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi adari to yatọ, to si fi ọkan ṣiṣẹ sin ipinlẹ Ondo ati awọn eniyan rẹ.

O ni ibanujẹ ti iku rẹ mu wa jẹ ẹru to wuwo lati gbe.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu jade láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe gomina ipinlẹ Ondo, lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, Amofin agba Rotimi Akeredolu SAN, ti jade laye.

Owurọ Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni iroyin naa jade sita pe o ku lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.

Ni nnkan bi aago meji oru la gbọ pe o mi eemi igbẹyin.

Ṣaaju iku rẹ, Gomina Akeredolu ti n ṣe aisan fun ọpọlọpọ oṣu.

Awọn iroyin kan sọ pe aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ, Leukemia, ni gomina naa ni.

Lati bi ọdun kan si lo ti wa ni idubulẹ, ti ko le ṣe iṣẹ rẹ gẹgẹ bi gomina.

Ninu atẹjade rẹ loju opo ayelujara X rẹ, gomina ana ni ipinlẹ Delta, Arthur Okowa ṣalaye pe iku rẹ jẹ adanu nla fun orilẹede Naijiria.

O ni akọni ti ko ṣe e fi ṣere paapaa pẹlu ẹmi ifọkansin, igboya ati ọgbọn inu rẹ jẹ eyi ti ko lẹlẹgbẹ rara.

Ọsẹ meji sẹyin ni Akeredolu fa iṣakoso ipinlẹ Ondo le igbakeji rẹ, Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa, lọwọ, ko le lọ fun itọju ara rẹ nilẹ okeere.

Eyi waye lẹyin to ti lọ fun isinmi ati itọju fun ọpọlọpọ oṣu, ko to o tun pada wa sile.

Ṣugbọn iroyin ti a ko ti i le fidi rẹ mulẹ ni pe boya orilẹ-ede Naijiria tabi ilẹ okeere lo ku si.

Awọn iwe iroyin kan sọ pe ilu Eko lo ku si, bẹẹ ni awọn iroyin miran tun sọ pe orilẹ-ede Germany lo ku si.