‘Iṣẹ́ ayàwòrán ló n gbé mi láti igbà tí àwọn òbí mi kò ti le gbọ́ búkàátà mi mọ́ ‘

‘Iṣẹ́ ayàwòrán ló n gbé mi láti igbà tí àwọn òbí mi kò ti le gbọ́ búkàátà mi mọ́ ‘

Ipele kẹta ni fasiti ni Basiru Barakat Bisola, wa nigba ti awọn obi rẹ ko ri owo ile ẹkọ rẹ san mọ.

Lati igba naa si lo ti n gbọ bukaata ara rẹ pẹlu iṣẹ ayaworan sara ogiri.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Omidan Bisola, to si kẹkọọ jade ni fasiti ipinlẹ Kwara.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC, Bisola sọ pe ọdun 2018 ni oun pinnu lati ma a ṣe iṣẹ ayaworan lẹyin to ran ọrẹ rẹ kan lọwọ nidi iṣẹ.

Botilẹ jẹ pe imọ nipa eto ilera ni Bisola kọ ni fasiti, o ni ko si ẹni kankan ti oun le ṣe to le fun oun ni awọn nnkan ti oun ti ni gẹgẹ bi ayaworan.

O ni lootọ ni ko si iṣẹ nita, ṣugbọn kii ṣe nitori owo ni oun ṣe n ṣe iṣẹ ayaworan.

Bisola ni oun ko kọ́ iṣẹ naa ni ibi kankan.

Ṣe ko si nnkan to dara, ko ma kù sibi kan.

Arabinrin ayaworan yii ni iṣẹ oun ko jẹ ki oun raaye fun faaji tabi yan ọrẹ, amọ o n gbọ bukaata oun, to si gba oun silẹ lọwọ airi iṣẹ ṣe.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí