Ẹ wo bí ẹbí àti ẹni tí wọ́n fẹ́ lọ yọ kíndìnrín rẹ̀ lókè òkun ṣe ń gbé nínú ìbẹ̀rù

Irinṣẹ awọn Dokita

Oríṣun àwòrán, JEFF OVERS/BBC

  • Author, Mark Lobel, Kate West and Melanie Stewart-Smith
  • Role, File on 4

Ipinu arakunrin kan to la iṣoro nla kọja ni ilu London to si sa lọ si agọ ọlọpaa to wa lẹgbẹ papakọ ofurufu Heathrow ni yoo jẹ aṣaju ninu ẹsun ẹjọ kan ti ilẹ UK yoo fi ṣide fifi imu awọn ọdaran agbeni-yọ-ẹya ara danrin.

Ikọ ọlọpaa Metropolitan ti fun ileeṣẹ BBC ni aṣẹ bayii lati ṣe iwadii nipa ẹsun to ti di ọkan ninu iwe itan bayii.

Daniel n gbọ iroyin kan ti yoo ba a lẹru ju nile aye rẹ fun igba akọkọ.

O jokoo si yara kan to wa fun ibeere ni ileewosan Free Hospital ni London to si n ba awọn dokita sọrọ pẹlu ede Gẹẹsi kekere to mọ ọ sọ.

Ẹni ọdun mọkanlelogun yii to jẹ ontaja oju popo tẹlẹ ni ipinlẹ Eko lorilẹede Naijiria wa si UK fun ohun ti wọn sọ fun un pe o n bọ wa ṣe ni eyi ti wọn ṣapejuwe bi “ohun ti yoo mu ayipada rere ba igbesi aye rẹ”. O ti ro pe iṣẹ to ta lẹnu kan ni oun n bọ wa ṣe.

Ṣugbọn ṣe ni awọn dokita bẹrẹ si ni sọ nnkan mii fun un nipa ewu to wa ninu ohun ti wọn gbe e wa ṣe ati iru itọju to nilo lati ni fun ara rẹ.

Asiko naa ni Daniel sọ fun awọn to n fọrọ wa a lẹnu wo pe oun woye pe kii ṣe ọrọ iṣẹ ni wọn tori rẹ gbe oun wa si UK bi ko ṣe lati wa yọ kindinrin rẹ fun eeyan ti ko mọ ri.

Wọn fẹ kun ẹran ara rẹ ni bi ẹran jijẹ lati yọ ohun ti wọn fẹ kuro lara rẹ ki wọn si ran an pa pada. Christine Huddlestone ti ẹgbẹ kan to n ja lodi si ifiniṣẹru sọ bẹẹ.

O wa jẹ anfani fun Daniel wipe awọn dokita ti bẹrẹ si ni fura pe ko mọ nnkan to n ṣẹlẹ ti o si kọ wọn lominu pe o da bii pe wọn n fi ipa mu u ni.Tori naa, wọn da igbesẹ yiyọ kindinrin naa duro.

Sibẹ lẹyin eyi, Daniel ko tii bọ tan yan yan lọwọ awọn onifayawọ to gbe e lọ oke okun.

Oju Daniel la si otitọ!

Sonia Ekweremadu ati Daniel

Oríṣun àwòrán, METROPOLITAN POLICE

Ni ile to n gbe, Awọn ọkunrin meji kan tun wa fi ọrọ wa a lẹnu wo. Ibẹ lo ti gbọ ọrọ kan ti wọn n sọ pe wọn fẹ da a pada si Naijiria lati lọ yọ kindinrin ọhun.

Lẹyin orun ọjọ meji ti ko tilẹ ri sun daadaa tori ibẹru, lo ba sa lọ si agọ ọlọpaa kan lẹgbẹ Heathrow, eyi si lo fa sababi iwadii akọkọ yii ti UK yoo dawọle to ni ṣe pẹlu ṣiṣe fayawọ eeyan kan lati lọ yọ ẹya ara rẹ.

Eyi ṣẹlẹ ninu oṣu Karun ọdun 2022, Daniel (Eyi kii ṣe orukọ rẹ gangan) ti n gbe labẹ amojuto ati abo to nipọn latọdọ awọn ọlọpaa bayii.

Ẹkunrẹrẹ iroyin ti BBC ṣe lori igbẹjọ yii lo jẹ ki wọn ri i pe igbẹjọ naa ti jẹ ki awọn alaṣẹ UK tun ri awọn ẹsun mii to ni ṣe pẹlu ṣiṣe fayawọ awọn eeyan wọ ilu wọn lati yọ ẹya ara wọn. Awọn niyii:

Ọkunrin ara orilẹede India kan to wa ni bii ọjọ ori to le ni ọgọta ti ko si panpẹ ọlọpaa UK lori ẹsun ifura pe o n gbimọ pọ lati fi ipa mu eeyan kan lati yọ kindinrin rẹ. Ibẹrẹ oṣu yii ni wọn fi ofin gbe e amọ wọn ti tuu silẹ pẹlu beeli.

Ajọ to n ri si ọrọ to ba ni ṣe pẹlu ẹya ara eeyan ti gbe ẹjọ kan le awọn ọlọpaa lọwọ to ni ṣe pẹlu pe awọn eeyan kan pada si UK lẹyin ti wọn ti lọ san owo fun yiyọ ẹya ara ni orilẹede mii lọna aitọ.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa Met ti ni awọn n tan ina wa awọn afurasi mii to ba daju nipasẹ iwadii awọn.

Ki ni itumọ “Organ Harvesting” yii gan?

Awọn Dokita

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyi ni itumọ rẹ lede Yoruba jẹ yiyọ ẹya ara eniyan. Awọn onimọ iṣegun oyinbo lo n pe e ni Organ Harvesting eyi to si ti wọpọ lẹnu awọn eniyan.

Yiyọ ya ara eniyan jẹ gbigbe ẹya ara eeyan kan jade lati gbe e sinu ẹya ara ẹlomiran to si jẹ pe ni ọpọ igba, fun ere jijẹ ni yala boya ẹni naa mọ tabi ko mọ si i tabi boya ẹni naa ko tilẹ fọwọ si igbesẹ naa.

Labẹ ofin to de ifini ṣẹru lọna igbalode, ẹni ti wọn ba fẹ yọ ẹya ara rẹ ko lee fọwọ si ki wọn ṣe bẹẹ fun un.

O saba maa n ni ọwọ irọ ninu tabi ṣiṣe ileri lati san ẹsan rere fun awọn ti wọn ba fẹ yọ ẹya ara wọn naa.

Bakan naa, ofin United Kingdom ti ọdun 2015 mẹnu ba ọrọ yiyọ ẹya ara eeyan to si ni o ni ijiya to to ki wọn fi ẹni naa si ẹwọn gbere.

Ẹya ara inu eniyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọgbọn ti awọn Ekweremadu da lati mu ara Daniel balẹ

Iyawo Ekweremadu, Beatrice ati Dokita wọn, Obeta

Oríṣun àwòrán, METROPOLITAN POLICE

Wọn gbe Daniel lọ si ọdọ dokita lọpọ igba ni ẹka to wa fun awọn alaisan ara ọtọ nileewosan London Royal Free Hospital.

Amọ magomago wọn yii kuna ti Daniel si lọ fi ẹjọ sun ọlọpaa. Ọrọ ẹnu rẹ lo mu ki awọn agbofinro ọtẹlẹmuyẹ lọ si ile Baba Sonia to jẹ ọkan lara awọn oloṣelu nla lorilẹede Naijiria.

Ike Ekweremadu jẹ Sẹnatọ ati ọlọrọ ti awọn ọmọ rẹ n lọ kawe ni oke okun.

Ninu igbẹjọ rẹ to waye nibẹrẹ ọdun yii, Ike Ekweremadu sọ pe awọn eeyan lo ṣi oun lọna ti oun ko si laye ni i lọkan lati fipa mu Daniel tabi fi ọwọ ọla gba a loju.

Koda, adajọ to da ẹjọ naa sọ pe Ekweremadu ti lọwọ si gbigbe ofin kan kalẹ pe ki wọn maa da sẹria fun ẹni ti wọn ba gba mu pẹlu yiyọ ẹya ara eniyan to lodi sofin ni Naijiria.

Too ba n gbero lati rinrinajo lọ oke okun lati yọ ẹya ara, ohun to yẹ koo mọ ree

Ara eniyan ti wọn rán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni oṣu Keje ọdun to kọja, sisan owo fun eeyan ki wọn yọ ẹya ara ni ilẹ England, Scotland ati ni Wales ti di irufin. Gbogbo awọn to ni ileewosan ni Great Britain lo ti ni aṣẹ ofin bayii lati fi ẹjọ ẹnikẹni to ba wa ba wọn nipa yiyọ ẹya ara tabi fun itọju lẹyin rẹ sun ijọba.

Onimọ iṣegun oyinbo nipa kindinrin to n gbe ni Birmingham, Dokita Adnan Sharif sọ pe “lootọ iwa ọdaran to nira lati fi ẹri rẹ han ni ṣugbọn a mọ pe o maa n ṣẹlẹ”.

“A beere lọwọ ajọ to n ri si ọrọ ẹya ara eeyan (HTA) pe ẹsun melo ni wọn ti gbe lọ fun awọn ọlọpaa lati igba ti ofin ti yi pada ni oṣu keje ọdun ti kọja.

Ọga agba ileeṣẹ ọhun, Ọmọwe Colin Sullivan sọ fun wa pe o ti kunwọ gidi gan – o tun fi kun un pe awọn dokita atawọn to ni ileewosan lo wa fi ẹjọ awọn ẹsun bẹẹ lọ awọn”.

O ni ajọ HTA ti ṣe atunto awọn oṣiṣẹ wọn to fi mọ imọ ẹrọ ileeṣẹ wọn lati pariwo iru iṣẹlẹ yii to ba lagbara.

Ifini ṣẹru igbalode àti bi ọwọ ṣe tẹ awọn to ṣe e

Ike Ekweremadu

Oríṣun àwòrán, METROPOLITAN POLICE

Ifini ṣẹru lọna igbalode lọpọ igba maa n nira lati gbe ẹri jade.

Ni ti Daniel yii, awọn ọlọpaa Met ti kọkọ ro pe ẹjọ yii yoo wọlẹ gan fun ọpọlọpọ ọdun tori awọn afurasi ti kuro ni orilẹede wọn.

Amọ ni ọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun 2022, Ọlọpaa, Det Sgt Andy Owen gba ipe kan wipe Ike Ekweremadu ati iyawo rẹ n bọ wa si London.

Bo ṣe sare ko awọn ikọ rẹ jọ niyẹn lati lọ duro de e ni papakọ ofurufu Heathrow, bẹẹ si ni awọn ọlọpaa sin tọkọ-taya naa jade latinu ọkọ ofurufu.

Awọn ọlọpaa gba foonu lọwọ wọn eyi to jẹ ki wọn ri aṣiri gbogbo igbesẹ wọn. Wọn gba awọn ọrọ to ṣe koko bii ọrọ atẹjiṣẹ nipa owo ti wọn fẹ san fun eeyan kan to fẹ fun wọn ni ẹya ara iyẹn miliọnu mẹrin abọ (£4,317 or $5,487).

“O kan da bii pe a n tu apoti ọrọ ni – Ṣe ni ọpọlọpọ aṣiri n tu jade”

Det Sgt Owen sọ fun wa pe “mo kan n ri ọpọlọpọ aridaju to le ṣakoba fun wọn ni to n tu jade puupuu.”

Amọ biba iru afurasi alagbara bayii wọ ẹjọ ko rọrun rara.

Koda wọn ni awọn Sẹnetọ Naijiria gbiyanju ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si orilẹede Naijiria.

Bakan naa, “wọn fẹ sunmọ ọmọ to fara gba yiyọ ẹya ara yii”, Det Supt Andy Furphy sọ eyi to si ni “o tan ina ọpọlọpọ ifura silẹ fun wa. Lọgan la woye pe ọmọ naa ko ni aabo to daju.”

Lẹyin ti wọn gba imọran ni ilana ofin, awọn ọlọpaa ni aṣẹ lati rii pe wọn ko ri aye sunmọ ọmọ naa.

Ẹka eto kan lori ileeṣẹ BBC, File on 4 ba Sẹnetọ to dari ikọ naa sọrọ, Adamu Bulkachuwa, o ṣe ibẹwo si Ekweremadu lọgba ẹwọn. “O sọ fun wa pe oun fẹ lo iṣan ibanidọrẹ ati ti ipo alaṣẹ lati fi tẹpẹlẹ mọ ijọba Britain lati wo o boya wọn yoo le mu iyanju ba ọrọ naa”.

Amọ Sẹnetọ Bulkachuwa ni eyi kii ṣe lati mu ki igbẹjọ ọhun dẹrun fun akẹgbẹ oun o amọ “toripe awa naa fọwọ si awọn ofin to lodi si ṣiṣe fayawọ lati yọ ẹya ara eeyan lagbaye”.

Ẹwẹ, Det Sgt Owen tun ṣalaye pe awọn eeyan ti ro pe Daniel kan jẹ ọkunrin kan to ja ara rẹ lati le ri aduru owo to ba le ri gba amọ bi o ṣe tun wa kọ owo gba ma binu ti awọn oniṣẹ laabi naa fẹ fun un ti yi itan erongba naa pada.

Det Sgt Owen sọ fun BBC pe: “Inu Daniel dun pe awọn gba a gbọ, o si kan fẹ tẹsiwaju pẹlu igbe aye rẹ.”

Ipo wo ni ẹbi Daniel wa ni Naijiria bayii?

Ẹgbọn Daniel ni ojojumọ ni baba ati iya awọn n sọkun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọja foonu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Baba onile Daniel to tun jẹ ẹni to n tọ ipasẹ rẹ gẹgẹ bi agbalagba to maa n gbọ ọrọ si lẹnu to si maa n ba sọrọ lojoojumọ ko to di pe wọn ko rii mọ ko gbagbọ pe Daniel yoo gba lati ta kindinrin rẹ.

“Tori o mọ pe awọn ọna mii wa lati pa owo. Koda ko jẹ £1m ni wọn fẹ fun un, ko ni ṣe e,” baba naa sọ bẹẹ.

Lọwọlọwọ, ẹru ko ba Daniel nitori abo ara rẹ. O wa labẹ akoso ati abo ọlọpaa UK to si woo pe oun ko ni le pada si orilẹede Naijiria. O le ma ri mọlẹbi rẹ mọ.

O da abo bo kindinrin ara rẹ o si kọ orukọ ara rẹ sinu iwe itan, ṣugbọn igbesi aye rẹ ti pin yẹlẹyẹlẹ bayii.