Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi

Oríṣun àwòrán, Emperor Abdulrasheed Adewale Akanbi Telu 1/faceboo

Igbimọ awọn alalufa ati Imaamu nilẹ Yoruba, Edo ati Delta ti ke si gomina ipinlẹ Ọsun pe ko ke si kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi pe ko tọwọ ọmọ rẹ bọṣọ lori ero gba rẹ lati yan Mufti agba fun ilẹ Yoruba.

Imaamu agba ipinlẹ Ekiti, Alaaji Jamiu Kewulere to ko igbimọ naa sodi lọ sọdọ gomina Oyetọla fẹsun kan Ọba Akanbi pe o n gbero lati fi Sheik Daud Mọlaasa joye Mufti qgba fun ilẹ Yoruba.

Igbimọ awọn alalufa ati Imaamu nilẹ Yoruba, Edo ati Delta ṣalaye ninu lẹta ti agbẹjọro wọn kọ ranṣẹ si gomina ipinlẹ Ọṣun, ileeṣẹ alaabo DSS, kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ naa, Wale Olokode woye pe awọn Imaamu atawọn alaafaa nikan lo lẹtọ lati lati fi eeyan si ipo naa.

Wọn ni ikọja aye, orun ori kẹkẹ ni igbesẹ ti Oluwo Akanbi fẹ gbe yii nitori ko si bi jijẹ oye Mufti Agba ṣe kan an.

“Nitori idi eyi ni a fi n pe akiyesi yin lori igbesẹ ti Oluwo fẹ gbe yii ki o to da wahala ẹsin silẹ laarin awọn ilu ekeyi to lew domi alaafia ru.”

Nigba ti BBC News Yoruba kan si Oluwo ti ilu Iwo lati gbọ ti igun rẹ lori ọrọ yii, O ni oun ko ni ọrọ kan lati sọ lori rẹ ṣugbọn ko si ẹni kan to lee fi ọwọ rọ oun ṣẹyin nilẹ Yoruba.

“Ni ilu Naijiria yii, ko si ẹni to lee fọwọ rọ Oluwo sẹyin. Mo ti di Ọba ti ẹnikẹni ko le fa sẹyin. Ọlọrun lo gbe wa kalẹ.”

Amọṣa, gomina Oyetọla ti ni oun yoo boju wo ọrọ naa