‘Báwo l’èèyèn ṣe lè sín ní London kó di ẹ̀ṣẹ̀ ní Nàìjíríà? Bí ẹ̀sùn ìjọba fún Nnamdi Kanu ṣe rí lójú wa rèé’

Nnamdi Kanu

Ajijagbara fun awọn to n pe fun Biafra, Nnamdi Kanu ti sọ ni waju adajọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun tuntun ti ijọba Naijiria fi kan an.

Ohun to ṣẹlẹ ni pe adajọ agba fun ijọba ṣe atunṣe awọn ẹsun ti wọn fi kan an ti wọn si gbe lọ siwaju ile ẹjọ – ẹsun idunkoko mọni ati ẹni to n da ilu ru.

Nibayii, ile ẹjọ tun ti sun igbẹjọ rẹ siwaju di ọjọ Kẹwa oṣu Kọkanla ọdun 2021, bakan naa wọn ti ni ko pada si ahamọ ajọ DSS.

Adajọ ile ẹjọ kọ iwe ti awọn agbẹjọro Nnamdi Kanu gbe wa gẹgẹ bi wọn ṣe woye rẹ pe “ko ri ẹsẹ fi mulẹ rara labẹ ofin ko si ni iyi rara”.

“Awọn ẹsun meje ti ijọba fi kan Nnamdi Kanu ko nitumọ rara labẹ ofin eyi ni Ejiofor sọ.

Idi ti a fi sọ eyi pe kii ṣe ẹsun rara ni pe eeyan ko lee sin niluu London ko si di ẹṣẹ ni Naijiria torinaa gbogbo ẹsun wọn ko lẹsẹ nilẹ labẹ ofin”.

Awọn ẹsun ti wọn tun ṣe ọhun ni:

  • Pe Kanu fi ọ̀rọ̀ tó sọ lorii rẹdio lati London nibi to ti n fi yiyapa ẹkun Guusu-Ariwa ati Guusu-guusu atawn apa ibi kan ni Kogi, Benue kuro lara Naijiria lati di Biafra.
  • Pe o fi eto ori rdio naa bu aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari nigba to pe aarẹ ni onifẹ biba ọmọde lopọ, agbesunmọmi, agọ ati aṣebi eeyan”.
  • Pe Kanu gbe ẹrọ to n mu rẹdio alaṣẹ ṣiṣẹ eyi to jẹ TRAM 50L to si lọ gbee pamọ si Ihiala, ipinlẹ Anambra.
  • Pe Kanu kede ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ Indigenous People of Biafra (Ipob) eyi ti ijọba Naijira ti gbe igi ofin le.
  • Pe Nnamdi Kanu ṣẹ si ofin nipa didun koko mọni nigba to fi ọrọ rẹ lori eto redio kan lati London gba awọn ọmọ ẹgbẹ Ipob nimọran lati ṣekolu si awọn agbofinro Naijiria atawọn bi wọn.

Lowurọ nigba ti igbẹjọ waye

Gbogbo ọna to lọ si ile ẹjọ giga ti ilu Abuja ni wọn ti di gbagba pẹlu bi awọn agbofinro ṣe wa nibẹ lati mojuto ọrọ abo nibi igbẹjọ ajijagbara fun Biafra, Nnamdi Kanu.

Ọpọlọpọ agbẹjọro lawọn ọlọpaa o jẹ ki wọ́n wọ inu ọgba ile ẹjọ naa.

Amọ iroyin ni ṣe ni wọn yọlẹ gbe Nnamdi Kanu wọle si ile ẹjọ ti awn eeyan dii ni waju ati lẹyin.

Nnamdi Kanu

Ijọba Naijiria ṣe atunṣe awọn ẹsun ti wọn fi kan an wọn si tun ko awn tuntun mii jade amọ ti wọn o tii fihan ni gbangba.

Ajijagbara yii la gbọ pe ijọba orileede Naijiria fi ẹsun igbesunmmi ati iditẹgbajọba kan an.

Bi wọn ba fi le da lẹbi ẹsun yii, ẹwọn gbere ni ijiya ti yoo jẹ ipin rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ti ṣe diẹ ti Nanamdi Kanu ti wa lahamọ lọdọ awọn ikọ ọtẹlmuyẹ DSS Naijiria gẹgẹ bi awọn agbẹjọro rẹẹ ti ṣe sọ.

Lọsẹ to kọja ni ijọba Naijiria mu iyipada ba awọn ẹsun ti wọn fi kan an ti wọn si tun sọ pe o lọwọ ninu ṣiṣe akoso ileeṣẹ to lodi ofin.

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe o lọwọ ninu titẹ awọn iwe ti ọrọ inu rẹ n bani lorukọ jẹ.

Awọn agbẹjọro rẹ ti ni ki ijọba ri wi pe wọn gbe Nnamdi Kanu wa si ileẹjọ lỌjọbi tii ṣe oni.

Boya yoo yọju tabi ko ni yọju, ipade di ileẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Niṣe ni ọkan awọn eeyan ko balẹ nigba ti awọn alaṣẹ ko gbe wa sile ẹjọ loṣu Keje lati wa jẹjọ.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, ikọlu ati iwa janduku orisirisi lo n waye ni ilẹ Igbo lati igba ti ijọba ti mu Kanu pada.

Koda,ni ọjọ Iṣẹgun to kọja yi awọn agbebọn kan pa ori ade meji nibi ipade awọn lọba lọba.

Oṣu Kẹwa ọdun 2015 ni wọn kọkọ mu Kanu ṣugbọn o sa ni Naijiria lọdun 2017 nigba ti awọn ọmọ ogun Naijiria yabo ile rẹ.

Idibo to n bọ lọna ni Anambra jẹ ọkan lara awọn nkan tawọn araalu n jaya si.

Pẹlu ikọlu ati iwa janduku eyi to ṣokunfa iku ọpọ awọn araalu ati agbofinro, ko si ẹni to le sọ boya idibo yi yoo waye lalaafia.