Gbas-gbos ti ń wáyé ṣáájú ìdìbò sí ipò gómìnà Osun, kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàrín Aregbesola, Oyetola?

Gboyega Oyetola ati Rauf Aregbesola

Saaju idibo sipo gomina ni ipinlẹ Osun, awọn alatilẹyin fun minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria, Rauf Aregbesola ati awọn alatilẹyin fun gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti koju oro si ara wọn.

Eyi ko ṣẹyin iṣẹlẹ to waye nibi ipade igun The Osun Progressives ti igun APC ni ipinlẹ Osun nibi ti awọn agbebọn ti ṣekọlu si ibẹ, ti wọn si n yinbọn lakọlakọ soke lasiko iṣẹlẹ naa.

Agbegbe Oranmiyan House, Gbongan Road ni ilu Osogbo ni iṣẹlẹ naa ti waye ni ọsan gangan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn alatilẹyin fun Aregbeṣọla da ẹbi ru awọn alatilẹyin fun gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola pe awọn lo wa ni idi ikọlu awọn agbebọn si ibi ipade awọn.

Awọn ti iṣẹlẹ naa soju wọn ni awọn ọlọja to wa ni agbegbe naa sare ti ile itaja wọn, ti olukaluku sa asala fun ẹmi wọn.

Osun

Oríṣun àwòrán, Others

Fidio to safihan iṣẹlẹ naa ni ọkọ dudu Sienna Sports Utility lo wa si ibi ipade naa ti awọn agbegbọn mẹta si bẹrẹ si ni yin ibọn lakọlakọ si gbogbo agbegbe naa, ti wọn si n rin wolu ibi ti wọn wa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ naa sa asala fun ẹmi wọn amọ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ, Razaq ni wọn lo koju awọn agbebọn naa ti wọn fi sa wọ inu ọkọ wọn pada ti wọn si lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni alaga ẹgbẹ The Osun Progressives, TOP, Lowo Adebiyi fẹsun kan gomina Adegboyega Oyetola ati awọn alatilẹyin rẹ ni igun Ileri Oluwa faction gẹgẹ bi awọn to wa ni idi iṣẹlẹ naa.

Amọ agbẹnusọ fun gomina Oyetola, Ismail Omipidan ni gomina Oyetola ko ni nkankan ṣe pẹlu iṣẹlẹ to waye naa.