Buhari ti sọ̀rọ̀ sókè lórí àbájáde ìwádìí EndSARS, ilẹ̀ Amẹ́ríkà sì ti fun lésì

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọrọ lori abajade iwadii EndSARS pẹlu idaniloju pe ijọba apapọ yoo faye silẹ lati tẹle awọn ilana gbogbo to yẹ.

O ni oun yoo duro de awọn esi to ba jade lawọn igbimọ oluwadii gbogbo ti awọn ijọba ipinlẹ kọọkan gbe kalẹ lati tanna wadii awọn iwa aṣemaṣe awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari sọ eleyi di mimọ nigba to n gba alejo akọwe fọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika Antony Blinken nilu Abuja.

Aarẹ ṣalaye pe ijọba apapọ ko lee fi aṣẹ tirẹ lelẹ lori awọn ọrọ naa nigba to jẹ pe awọn ipinlẹ ti gbe igbimọ kalẹ ti wọn si ti fun awọn igbimọ yii ni gbedeke ohun ti wọn yoo ṣe.

Ninu ọrọ tirẹ, akọwe ọrọ okeere nilẹ Amẹrika, Antony Blinken ni igbesẹ to loorin fun idagbasoke eto ijọba tiwantiwa; bẹẹ lo yannana rẹ pe ko si ibi ti iṣe ko si nitori pe orilẹede Amẹrika naa ni awọn iṣoro aṣemaṣe ọlọpaa.